O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ṣe bi ẹ oo ṣe maa wo ọkunrin Fulani ilẹ Yoruba yii ree

Ko too di pe ijọba Buhari yii de, a ko gbọ ariwo tabi orukọ Ọba Fulani nibi kankan nilẹ Yoruba, bo tilẹ jẹ pe a maa n gbọ awọn ọba Hausa laarin wa. Ṣugbọn ọba Hausa yii naa ki i ṣe ọba bẹẹ, olori awọn Hausa adugbo kan lasan ni, aarin Saabo ni yoo si wa, ko si si ẹni ti yoo gbọ ariwo rẹ nibi kankan. Ṣugbọn nnkan ko ri bẹẹ mọ bayii, nitori nigba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu Eko yii fẹẹ du ipo, Ọlọrun nikan lo mọ bo ṣe mọ aafin olori awọn Fulani to sọ ara rẹ di Ọba Fulani, Muhammed Abubakar Bambado. Araalu ko gbọ pupọ nipa rẹ ri, afi nigba idibo naa. Awọn Sanwo-Olu lọ si aafin ọba yii, nigba naa ni awọn eeyan ri ohun to wa nibẹ, ati bi aafin naa ṣe fẹrẹ ju ti Ọba Eko lọ. Ki i waa ṣe iyẹn ni, bi ko ṣe agbara ti ọkunrin naa ni, debii pe a ko gbọ Seriki Hausa mọ, ọkunrin naa lo ku to da bii olori fun ọba Hausa ati Fulani ni gbogbo ilẹ Yoruba yikayika, nitori o loun ki i ṣe olori Fulani ipinlẹ Eko nikan, pe ti gbogbo ilẹ Yoruba ni. Ko si ohun to buru bi awọn alejo kan ba ko ara wọn jọ nibi kan, ti wọn si yan olori tiwọn, ṣugbọn nigba ti olori naa ba n ta kan-n-gbọn pẹlu awọn oniluu ni wahala yoo bẹrẹ. O daju pe ko si ibikibi nilẹ Hausa ti wọn yoo ti gba iru iyẹn. Ko si ara ti ọkunrin to n pe ara rẹ ni Ọba Fulani ilẹ Yoruba yii ki i da o: aafin nla bii ti ọba gidi, awọn iranṣẹ loriṣiiriṣii ti wọn yoo maa jokoo yi i ka, awọn ẹṣọ pẹlu ohun ija lọwọ wọn, bẹẹ si ni bo ba n lọ pẹlu ẹṣin, tabi to ba n lọ si ode pẹlu ọpọlọpọ mọto, o loju ọba Yoruba ti yoo duro lẹgbẹẹ rẹ bo ba de ibi ayẹyẹ kan. Gẹgẹ bi awọn Fulani ti i maa i ṣe, bii ere ni kinni yii bẹrẹ, pẹlu ọgbọn ati ẹtan, ṣugbọn ni bayii, o ti di nla, awọn oloṣẹlu wa lo si tubọ ba nnkan jẹ fun wa. Awọn oloṣelu wa lo n paara ọdọ olori awọn Fulani yii, nitori wọn yoo ni ki wọn dibo fawọn. Nidii eyi, ọkunrin Bambado yii sọ lọsẹ to kọja pe ati oun o, atawọn ọmọ oun o, ko si ipo kankan ti awọn ko le du ni Eko yii, nitori Eko ni wọn bi oun si, Eko yii si loun bi awọn ọmọ oun naa si, ko si si ipo oṣelu kan ti yoo yọju ti wọn yoo ni oun ko le du u, tabi pe ko tọ si ọmọ oun. Itumọ eyi ni pe laipẹ lai jinna, ọmọ olori awọn Fulani yii yoo du ipo gomina Eko niyẹn o. Bo ba jẹ gbogbo ẹni ti wọn ba bi sibi kan ni i jọba nibẹ, Ọmọ Abẹokuta iba jọba Kano, ṣugbọn o daju pe awọn ara Kano ko ni i gba iyẹn. Yoruba nikan ni ki i ka iru eleyii si tẹlẹ, nitori Yoruba ko alejo mọra gan-an. Ṣugbọn awọn to ku ko ri wa bẹẹ, bi ija ba ti de kẹrẹ nilẹ Hausa, ile awọn Yoruba ati awọn ajoji mi-in lawọn ọmọ ibẹ maa n wa kiri, ti wọn yoo si maa pa wọn lai fi ti pe wọn ti wa nibẹ tipẹ ṣe. Gbogbo raurau tawọn n dan wo yii, ko si ẹni ti yoo lọ siluu wọn lọọ dan an wo, wọn yoo juwe ile baba tọhun fun un. Nigba ti ọkunrin yii ti waa jokoo si arin wa yii, to si sọ ara rẹ di olori, igba meloo lawọn Fulani yoo fi rọ kun ilẹ yii, ati awọn Fulani to jẹ ọmọ Naijiria ati awọn ti wọn jẹ ara orilẹ-ede mi-in. Ijọba atawọn oloye Eko gbọdọ fi opin si iwa ta-ni-yoo-mu-mi to fẹẹ di iwa awọn ajoji laarin wa yii o. Awọn ijoye Eko gbọdọ dide, ko gbọdọ si ọba Fulani nibi kan l’Ekoo, nitori ko si oye bẹẹ ninu ilana wa. Bi olori Fulani ba wa ni agbegbe kan, labẹ ọba agbegbe naa ni yoo wa, ki i ṣe ki olori Fulani kan sọ ara rẹ di ọba nla kan laarin wa. Ẹ kilọ fawọn oloṣelu aarin wa ki wọn ma ta Yoruba soko ẹru pata, ki wọn ma faaye gba awọn Fulani ki wọn ko ogun ja wa niluu yii lọjọ kan. Ẹ tete ṣe ohun to ba yẹ kẹ ẹ ṣe ki nnkan too bajẹ, giragira olori awọn Fulani Eko yii ṣẹẹ n pọ ju o.

 

Ẹ gbọ, ta la ri ba wi bi ko ṣe Ọba Akiolu, Elekoo

Nigba ti ọba kan ba wa ti ko fi ti awọn eeyan rẹ ṣe, tabi ti ko ka awọn eeyan rẹ si kinni kan, araata ni yoo gba ipo apọnle to wa lọwọ rẹ, yoo si di eeyan yẹpẹrẹ. Wahala to ṣẹlẹ si ọba Eko ṣoju wa lasiko iwọde SARS, o si fi han bi ọba naa ko ṣe niyi kan laarin awọn eeyan rẹ, koda, nitosi aafin rẹ gan-an. Ohun ti ko si jẹ ki Ọba Rilwanu Akiolu niyi bayii, ẹni to ba wo fidio kan to ṣe jade lọsẹ to kọja yoo ri i. Ninu fidio naa, Akiolu ni oun ni ọba Eko, boya awọn kan fẹ o, boya wọn ko fẹ o, oun ni Ọba le gbogbo wọn lori, ko si sohun tẹnikan ninu wọn le ṣe. Lo ba bẹrẹ si i sọ oyinbo lọ bii ilẹ bii ẹni, lo kewu lọ rai, bii ẹni pe ọba ilu oyinbo ni, ki i ṣe ọba Yoruba, tabi pe oun lọba wọn nilẹ Larubawa ti kewu dun mọ ọn lẹnu. Ọrọ ti Akiolu sọ ki i ṣe ọrọ agba to fẹẹ pari ija, ọrọ agbalagba to mura ija pẹlu awọn to n ṣẹjọba le lori ni. Ko si bi eeyan yoo ṣe maa ṣe bẹẹ ti yoo niyi loju awọn araalu rẹ, bi wọn ṣe ṣe fun un lọjọsi yii naa ni wọn yoo maa ṣe fun un. Inu buruku ni agba n ni, agbalagba ki i lọrọ buruku lẹnu; bẹẹ lo jẹ pe agba to ba wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri. Bi Akiolu ba n binu, ki i ṣe gbangba bẹẹ ni yoo ti maa fa ibinu rẹ yọ, nitori o ni iwa ti ọba gbọdọ hu lawujọ. Paripari rẹ ni pe awọn wo ni Ọba Akiolu n ba sọrọ gan-an. Ṣe awọn ọmọ Yoruba Eko lo n sọ ede oyinbo ati kewu si. Aṣe pe ede Yoruba n dojuti i ni gbangba niyẹn o, tabi pe to ba sọ Yoruba, awọn ọmọ Yoruba to fẹẹ sọ ọ fun ko ni i gbọ. Boya to ba si fi ede Yoruba ṣadura, adura naa ko ni i de ọdọ Ọlọrun ni. Nigba ti a ba pe eeyan ni ọba Yoruba, to fẹẹ ba Yoruba sọrọ, to da oyinbo palẹ, to fẹẹ ṣadura, to mu kewu ke bii Lemọọmu ayelujara. Ṣe iru ọba bẹẹ ko mọ pe oun n ta Yoruba lọpọ ni, ko mọ pe oun n fabuku kan iran oun ni, ko mọ pe oun n sọ pe ede ati aṣa awọn baba oun ko jẹ kinni kan ni, ati pe ede ti oun n sọ yii ni olori fun ede toun, ati aṣa awọn baba toun. Bẹẹ bi wọn ba fẹẹ jọba, wọn yoo maa sare kiri, wọn yoo maa bẹbẹ, wọn yoo ni Yoruba lawọn fẹẹ wa gbe ga. Awọn ọba aferugbabukun wọnyi, nigba wo ni awọn alalẹ Yoruba ko ni i binu si wọn. Iru wọn si pọ nilẹ Yoruba. Ṣugbọn ipo pataki ni Akiolu di mu, ko yee soyinbo sara Eko mọ, ko sọ Yoruba to tori ẹ gba ipo ọba, ko ma si laju silẹ ki awọn alejo gba Eko lọwọ ẹ, ko ma di ohun ti Fulani yoo le e danu nipo ọba lọjọ kan. Ẹ foṣelu silẹ, ọba to ba n ṣoṣelu ki i niyi lawujọ.

 

Ni ti yunifasiti LAUTECH, o yẹ ki oju ti awọn agbalagba yii ni

O dun-un-yan pe Bọọda Isiaka Ajimọbi ti ku, ṣugbọn nibikibi to ba wa naa, alaye ọrọ yii yoo maa ba a. Raufu Arẹgbẹṣọla wa ni Abuja, ko maa gbọ. Alao Akala wa ni Ogbomọṣọ, koun naa gbọ nibẹ, bẹẹ naa si ni Ọlagunsoye Oyinlọla niluu Okuku. Gbogbo awọn wọnyi ni wọn ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ ati ti Ọṣun. Ṣugbọn  gbogbo wọn naa ni wọn yanju ọrọ LAUTECH, yunifasiti nla to jẹ ti awọn ipinlẹ mejeeji. Asiko kan naa ni Alao Akala ati Oyinlọla ṣe gomina l’Ọyọọ ati l’Ọṣun, ọrẹ si ni wọn, ṣugbọn wọn yanju ọrọ LAUTECH yii ti, bẹẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn mejeeji yii o. Ni gbogbo asiko ti awọn yii fi n ṣe gomina, awọn APC fẹrẹ bu wọn pa, wọn ni to ba jẹ awọn ni, awọn yoo yanju ọrọ naa kia. Nigba ti Ọlọrun yoo ṣe e, Arẹgbẹ ati Ajimọbi di gomina, ACN ni wọn jọ n ṣe ki wọn too di APC, aṣaaju ẹgbẹ wọn si ni Bọla Tinubu i ṣe. Bọla Tinubu yii, awọn yii naa ni wọn fi ṣe baba isalẹ fun yunifasiti naa, wọn ni yoo mu daadaa ba wọn. Ṣugbọn ati Arẹgbẹ, ati Ajimọbi, ati Tinubu funra ẹ, wọn yanju ọrọ naa ti: igberaga, emi-ni-mo-jaja-to-bayii ati imọtara-wọn-nikan ko jẹ ki wọn le ba ara wọn sododo, ki wọn si yanju ọrọ lori ohun ini awa ọmọ Yoruba. Tabi ki lo na wọn? Ki ọkunrin ri ejo, ki obinrin pa a, ṣebi ki ejo ma ti lọ ni. Bi LAUTECH ba wa ni Ọyọ, ṣe ki i ṣe ilẹ Yoruba ni. Tabi to jẹ Ọṣun naa lo wa, ṣe ki i ṣe ilẹ Yoruba ni. Ọlọrun nikan lo mọ bi awọn agbalagba wọnyi ti ṣe ronu, ti ironu naa si dorikodo pata, nitori ironu ti ko mu anfaani kankan fun wa nilẹ Yoruba ni, ijiya to si ti idi iwa wọn yii wa fun awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ yunifasiti yii, eeyan ko gbọdọ ṣadura pe ki Ọlọrun san awọn oloṣelu wọnyi lẹsan to ba tọ si wọn ni. Ẹ waa wo awọn gomina tuntun meji yii, Ṣeyi Makinde ati Gboyega Oyetọla. Ọna yoowu ti awọn gba ti wọn fi yanju ẹ, ko sẹni to fẹẹ beere, ohun ti inu gbogbo eeyan dun si ni pe wọn yanju ọrọ naa laarin ara wọn, ijọba si ba wọn fọwọ si i. Ohun ti wọn n pe ni ijọba ati agbọye niyi. Makinde ki i ṣe ọmọ APC, bẹẹ ni Adegboyega ki i ṣe ọmọ  PDP, ṣugbọn wọn ri ọrọ yii bii ọrọ to kan gbogbo Yoruba, wọn si ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ọrọ oṣelu yatọ si idagbasoke ilu ati agbegbe ẹni, ẹni to ba fi idagbasoke awọn ẹya rẹ silẹ to gba oṣelu mu, yoo jẹbi gbẹyin ni. Oṣelu lawọn Arẹgbẹ waa ṣe, ati Oyinlọla pẹlu Alao Akala, ṣugbọn loju wọn, lai ti i ku, Ọlọrun ti ba Yoruba ṣe ohun to ṣoroo ṣe loju wọn. O yẹ koju ti wọn ni. Ṣugbọn oloṣelu ko lojuti, bẹ ẹ ba ri wọn lode, wọn yoo bẹrẹ si i ko agbada iranu kiri, wọn yoo ni ko si bi awọn ko ti jẹ. Oṣelu nikan ni wọn waye wọn waa ṣe. Ẹ wo o, ẹ sun mẹyin o jare!

 

Fayoṣe ati Tinubu, Ọlọrun ma jẹ ẹ tanra yin pa!

Ọrọ ti Peter Ayọdele Fayoṣe n sọ ko le tete yeeyan, nitori ọrọ oloṣelu ki i yeeyan daadaa, afi ti eeyan ba mọ iru ohun ti oloṣelu bẹẹ n fẹ. Iroyin ti awọn kan gbe jade ni pe Fayoṣe sọ pe Aṣiwaju Bọla Tunubu ni aṣiwaju iran Yoruba patapata, pe ba a fẹ, ba a kọ. Awọn mi-in si gbe e jade pe ọkan ninu awọn aṣaaju ilẹ Yoruba ni Bọla Tinubu, wọn ni ohun ti Fayoṣe sọ niyẹn. Dajudaju, bi oloṣelu ba ti n sọrọ oloṣelu ẹgbẹ rẹ bayii, o ni kinni kan to n wa. Ọjọ kan n bọ ti gbogbo ilu yoo mọ ohun ti Fayoṣe n wa gan-an. Ṣugbọn ni ti ọrọ to sọ yii, keeyan ma lọ jinna lori ẹ, yoo ṣoro ki Yoruba too gba pe Tinubu ni aṣaaju awọn. Bo ba ṣe pe ọkan ninu awọn aṣaaju Yoruba ni, ko si ohun to buru ninu iyẹn, nitori aṣiwaju pọ nilẹ Yoruba, beeyan ba pe e ni ọkan ninu awọn aṣaaju wa, tọhun ko jẹ ayo pa. Ṣugbọn ẹni ba pe Tinubu ni olori ọmọ Yoruba pata nikan lo fẹẹ gbọ ọrọ mi-in lẹnu awọn eeyan, nitori ni tootọ, Tinubu ki i ṣe olori ọmọ Yoruba pata, oloṣelu lasan loun, oloṣelu ko si le jẹ olori iran kan, paapaa, bo ba jẹ iru oṣelu ti awọn n ṣe laye ode oni ni. Ẹni ti yoo jẹ olori awọn ẹya kan, yoo ran iru ẹya bẹẹ lọwọ, yoo ṣe oore ti wọn ko ni i le gbagbe laye fun wọn. Awolọwọ lo fun Yoruba ni ẹkọ-ọfẹ nigba ti oju dudu gan-an, ẹkọ-ọfẹ yii si ni Yoruba fi ta gbogbo ẹya to ku ni Naijiria yọ titi doni. Ta ni yoo waa sọ pe Awolọwọ ki i ṣe aṣaaju wa, bẹẹ ọdun marun-un pere lo fi ṣe olori ijọba ilẹ Yoruba naa. Ṣugbọn Tinubu lo ọdun mẹjọ, igba kan si wa to jẹ oun naa ni olori awọn gomina gbogbo to jẹ nilẹ Yoruba pata, oun lo n fi wọn sipo naa pẹlu owo rẹpẹtẹ. Ṣugbọn ki gan-an ni a oo tọka si pe Tinubu ṣe fun Yoruba o. Ṣebi loju Tinubu lawọn Fulani ṣe n fiya jẹ wa, loju ẹ ni ijọba Buhari yii ṣe n gba ohun gbogbo to tọ si ọmọ Yoruba to n gbe e fun ẹya mi-in, bẹẹ Tinubu yii lo gbe Buhari waa ba wọn. Loju Tinubu yii, ati lasiko ti oun n ṣe olori oloṣelu adugbo wa yii, ina Yoruba ko jo siwaju, ajorẹyin ni, ohun gbogbo ti ko si ṣẹlẹ ri bẹrẹ si i ṣẹlẹ laarin wa. Bi gbogbo rẹ ba si ṣẹlẹ, bi wọn n pa ọmọ Yoruba, ti wọn n ji ọmọ Yoruba gbe, Tinubu yii ko ni i sọ pe oun ri wa, bẹẹ okoowo ati awọn ibi ti oun ti n ri owo wa nibẹ ti ko bajẹ, o tubọ n le si i ni. Eyi ni pe bi Tinubu ba jẹ ọmọ Yoruba, to si n ṣe oṣelu nilẹ Yoruba, oun kan n fi oṣelu ilẹ Yoruba naa tun aye ara tirẹ ati ti awọn ọmọ rẹ ṣe ni, iyẹn ni pe o n fi orukọ Yoruba jẹun lasan. Iru ẹni bẹẹ ko le jẹ aṣiwaju iran kankan, ka ma ti i sọ ti Yoruba to jẹ iran awọn ọlaju pata. Nitori bẹẹ, ẹ sọ fun Fayoṣe ko wa ọrọ mi-in sọ jare, Tinubu ko le jẹ Aṣiwaju ọmọ Yoruba afi ti wọn ba jọ n tan ara wọn jẹ nikan. Bo a si jẹ wọn n tan ara wọn jẹ naa ni, afi ka gbadura fun wọn pe, “Ọlọrun ma jẹ ẹ tanra yin pa!’

Leave a Reply