Wọn la maneja banki mẹwọn l’Ekoo, ọgọsan-an miliọnu naira lo poora mọ ọn lọwọ

Faith Adebọla, Eko

Ọgba ẹwọn to wa l’Alagbọn, Ikoyi, nipinlẹ Eko, nile-ẹjọ giga tijọba apapọ kan paṣẹ pe ki wọn sọ maneja banki Zenith kan si, wọn lọkunrin naa ko le ṣalaye bi ọgọsan-an miliọnu naira ṣe dawati mọ ọn lọwọ ni banki ọhun, bẹẹ wọn lowo naa ki i ṣe tiẹ.

Ninu alaye ti agbefọba, Mọrufu A. Animashaun, ṣe niwaju adajọ lori ẹsun ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, o ni ki i ṣe ẹẹkan ṣoṣo ni afẹẹri ba owo tuulu tuulu yii o, iwadii ti fihan pe laarin ọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun 2010, si ipari ọdun 2019, lowo naa sọnu.

Mọrufu ṣalaye pe ọwọ kọsitọma banki ọhun kan, Dokita Jude Eugene, alaṣẹ ileeṣẹ Global Select Investment Services,  ni maneja afurasi ọdaran yii pẹlu awọn meji mi-in ti wọn n gbe ni Ojule keji, Opopona Balogun, Ikoyi, ti gba owo rẹpẹtẹ naa, wọn lawọn fẹẹ fi ba a ko awọn ọja kan wọle lati ilu oyinbo, tawọn ba si ti ta ọja naa tan, wọn yoo da owo ati ere pada sinu akaunti rẹ.

Wọn ko ọja ọhun wọle loootọ, wọn ta a, wọn si jere, ṣugbọn inu akaunti maneja ni wọn da owo pada si, dipo ti Dokita Jude, wọn waa purọ fun olowo pe awọn ọja ti wọn ra naa, feeki lo pọ ju ninu ẹ, wọn lo ti bajẹ ko too de Naijiria, awọn o ri i ta. Lẹyin eyi ni wọn nawo naa laarin ara wọn.

Mọrufu ni iwa gbaju-ẹ ni wọn hu fọkunrin naa, ohun ti wọn ṣe si ta ko ofin banki Zenith. Ẹsun lilu jibiti, igbimọ-pọ lati huwa buruku ati lilo ipo ẹni lati rẹ ẹlomi-in jẹ ni wọn ka si i lẹsẹ, eyi to ni ijiya labẹ isọri kọkanlelogoji ati mẹwaa din nirinwo iwe ofin iwa ọdaran ijọba apapọ ti ọdun 2004 ati 2006.

Olujẹjọ loun ko jẹbi ẹsun yii, ni lọọya rẹ, Richard Ahaomarugho, ba bẹ ile-ejọ ki wọn faaye beeli silẹ fonibaara oun, ṣugbọn Adajọ Austine Chuka Obiozor sọ pe ki wọn ṣi taari olujẹjọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ti wọn yoo gbọ ẹbẹ rẹ fun beeli.

O ni kawọn agbofinro tubọ tẹpẹlẹ mọ wiwa awọn afurasi ọdaran yooku ti wọn sa lọ.

Leave a Reply