Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Eeyan meji lo jẹ Ọlọrun nipe laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, nibi ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ lọna Iwo si Ibadan, nigba ti eeyan meji mi-in si n gbatọju lọwọ nileewosan latari bi wọn ṣe fara pa nibẹ.
Laago mẹwaa kọja iṣẹju mẹẹẹdogun aarọ ni mọto Lexus ES300 alawọ dudu to ni nọmba AKD 664 GF, ati ọkada Bajaj Boxer pupa kan kọ lu ara wọn.
Eeyan mẹrin; ọkunrin mẹta ati obinrin kan la gbọ pe wọn lugbadi ijamba ọhun, ṣugbọn loju-ẹsẹ ni ọkunrin kan ati obinrin kan jade laye.
Alukoro ileeṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe wọn ti ko oku mejeeji lọ sileewosan Jẹnẹra niluu Iwo, nigba ti awọn to fara pa wa nileewosan naa fun itọju.
Lara awọn ẹru ti wọn ba nibẹ ni baagi apamọwọ obinrin kan, eleyii ti foonu meji wa ninu rẹ, kaadi idanimọ ti orileede yii ati ẹgbẹrun kan aabọ naira.
O ṣalaye pe awọn ọlọpaa ilu Iwo ti n gbe igbesẹ lati wọ mọto ati ọkada naa lọ si ọfiisi wọn.