Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, ni wọn ni awọn ikọ afẹmiṣofo nni, Boko Haram, lọọ ka awọn agbẹ kan mọ inu oko irẹsi kan ti wọn n pe ni Garin-Kwashebe, nibi ti wọn ti n kore irẹsi, ti wọn si bẹ awọn bii mẹrinlelogoji lori da silẹ ninu wọn labule, Zabarmari, nipinlẹ Borno.
Ọkan ninu awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin to wa lati agbegbe naa, Ahmed Satomi, lo sọ eleyii di mimọ. O ni lasiko ti awọn eeyan naa wa ninu oko ti wọn n kore irẹsi ni awọn afẹmiṣofo yii ya bo wọn, ti wọn si bẹ bii mẹrinlelogoji lori ninu wọn.
ALAROYE gbọ pe eyi ko sẹyin iṣẹlẹ to waye ni ọjọ Ẹti, Furaidee, nibi ti awọn eeyan abule naa ti mu ọkan ninu awọn ikọ afẹmiṣofo to ti n yọ awọn eeyan agbegbe naa lẹnu, ti wọn si gba gbogbo awọn ohun ija to n lo lọwọ rẹ.
Ọkunrin yii ni awọn agbẹ atawọn apẹja lo ba iṣẹlẹ naa lọ ju, nitori niṣe ni wọn di wọn mọ, ti awọn eeyan naa ko si rọna sa lọ, eyi ti wọn fi pa wọn lapafọn.
Aṣofin yii ni ọjọ Aiku, Sannde, lawọn yoo sinku awọn eeyan mẹrinlelogoji ti wọn pa ọhun.