Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi ta a fi pari iroyin yii ni ọpọ eeyan niluu Agọ-Iwoye ṣi n binu si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun. Eyi ko ṣẹyin atunṣe oju ọna Igan, to ti bajẹ kọja aala, ti Aṣofin Adeṣẹgun Adekọya to n ṣoju ẹkun naa l’Abuja bẹrẹ si i tunṣe laipẹ yii, ti gomina si paṣẹ pe ko dawọ iṣẹ duro nibẹ, nitori ọna naa ki i ṣe tiẹ, tijọba ipinlẹ Ogun ni.
Awọn to n gba ọna Igan yii kọja royin ohun ti oju wọn maa n ri pẹlu bi ọna naa ṣe ti bajẹ to, paapaa awọn akẹkọọ ileewe Yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ to jẹ ibi ti wọn yoo gba kọja ree. Wọn ni ọna ọhun ko ṣee gba mọ fun mọto ati ẹlẹsẹ, o buru gidi.
Bo ṣe ti bajẹ kọja afarada, ti ijọba ko si ya si ọna yii, ni ALAROYE gbọ pe o fa a ti aṣofin ọmọ ẹgbẹ PDP to n ṣoju Ariwa Ijẹbu, Ila-Oorun Ijẹbu ati Ogun Water Side l’Abuja naa ṣe bẹrẹ atunṣe ọna yii lọwọ ara rẹ, ti ọmọ bibi Agọ-Iwoye naa si ko awọn oṣiṣẹ sibẹ pe ki wọn bẹrẹ iṣẹ nibẹ ni pẹrẹwu.
Ṣugbọn nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ọhun lọ ni aṣẹ ti de lati ileeṣẹ to n ri si iṣẹ ode nipinlẹ Ogun. Ẹnjinnia Adeṣina Babatunde to jẹ Oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lori iṣẹ ati nnkan amayedẹrun lo fi lẹta ṣọwọ si Adeṣẹgun pe ko dawọ atunṣe ọna naa duro kia, nitori ko gba aṣẹ ko too maa tun un ṣe, ati pe ọna naa ki i ṣe tiẹ, ijọba ipinlẹ Ogun lo ni in.
Lẹta naa ka siwaju pe bi aṣofin yii ba fẹẹ ṣe atunṣe ọna yii tabi eyikeyii ọna, niṣe ni ko kọwe si ileeṣẹ iṣẹ ode fun aṣẹ lati ṣe bẹẹ, ki i ṣe pe yoo maa da ọwọ wu lapo ara rẹ, ti yoo maa gba ojuṣe ijọba ṣe.
Ọjọ Ẹti to kọja yii ni lẹta naa balẹ gudẹ, latigba naa ni iṣẹ si ti duro loju ọna Igan gẹgẹ bii aṣẹ ijọba.
Iṣẹ to duro yii ko dun mọ awọn eeyan to n koju wahala nitori ọna yii ninu, niṣe ni wọn si koro oju si aṣẹ to ti ọdọ Gomina Abiọdun wa yii. Wọn ni bi gomina ko ba le ṣe ọna naa lati ọdun to ti bajẹ, ko yẹ ko tun di ẹlẹyinju aanu to fẹẹ tun un ṣe lọwọ lati ma ṣe e.
Ọpọ awọn eeyan ti ko le jade sọrọ yii ni wọn n sọ ọ soju opo ayelujara pe ohun ti gomina ṣe yii ko daa rara, wọn ni o ti fi oṣelu ṣaaju igbaye-gbadun awọn eeyan to dibo fun un.