Ọlawale Ajao, Ibadan
“Ọlọkada to ba tun dana sun agọ ọlọpaa tabi kọ lu agbofinro yoo gba pe oun ṣi ile aye wa.”
Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, lo ṣekilọ yii fawọn ọlọkada ninu ipade to ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ ọhun jake-jado ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Olugbenga Fadeyi, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan lọjọ Aiku, Sannde, to kọja, CP Enwonwu sọ pe ọpọ rogbodiyan to yọri si òfò ẹmi ati dukia ni ipinlẹ yii lẹnu ọjọ mẹta yii lo lọwọ awọn ọlọkada ninu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Iwadii ti awọn ọtẹlẹmuyẹ wa ṣe fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọkada ni wọn dana sun agọ ọlọpaa Idi-Ogungun, to wa l’Agodi, n’Ibadan, ati teṣan kekere to wa l’Agodi Gate, n’Ibadan, lasiko ija to waye laarin awọn pẹlu awọn alakooso ọgba ẹwọn Agodi lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020 yii.
“Teṣan ti wọn dana sun yii lakọọkọ agọ ọlọpaa n’Ibadan, nitori lati asiko ijọba amunisin ni wọn ti kọ ọ lọdun 1926, ko tilẹ too di pe orileede Naijiria gbominira rara.”
O waa kilọ fawọn to n fi alupupu ko ero kiri igboro lati kọwọ ọmọ wọn bọṣọ, nitori bi wọn ba tun ba dukia ọlọpaa kankan jẹ nibikibi ni ipinlẹ yii, oju ọdaran pọnbele nileeṣẹ ọlọpaa yoo fi wo wọn, awọn ko si ni i bikita lati ri i pe iya to le koko lo jẹ wọn labẹ ofin.