Ki i ṣe tuntun mọ pe ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ ti fori ẹjọ ti wọn pe ta ko oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ, Alfa Samuel Babatunde, ti sibi kan loṣu to kọja. ALAROYE wa iyawo wolii ọhun, Ajihinrere Bisọla Alfa, kan lati le fidi ododo mulẹ lori bọrọ ṣe jẹ gan-an mulẹ. Eyi lawọn nnkan to ba akọroyin wa, OLUṢẸYẸ IYIADE, sọ.
ALAROYE: Ki lẹ ri si iṣẹlẹ to gbe ọkọ yin, Wolii Alfa Babatunde, de ibi ti wọn wa lọwọlọwọ?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Ẹ wo o, bii ala lọrọ naa si n jọ loju mi lati ọjọ kẹwaa, osu kọkanla, ọdun 2019, tisẹlẹ yii waye, iya aimọdi lọkọ mi n jẹ, lẹyin Ọlọrun, emi ni mo tun sun mọ ọn ju laye ati lọrun, mo le fi gbogbo ọmọ ti mo bi bura ti wọn ba mọ ohunkohun lori ọrọ ọmọ ti wọn lo sọnu ninu ṣọọsi wa.
Ori pẹpẹ ninu sọọṣi lọhun-un lawọn wa laaarọ ọjọ naa nigba tawọn ọmọ wa loju titi, nibi ta a ta kanopi si fun wọn, niwọn igba ti ko ti i saaye ninu gbọngan ijọ wa. Lati aarọ ti wọn lọmọ ti sọnu, aago mẹta ọsan ti kọja daadaa ki wọn too jẹ ki Baba gbọ nibi ti wọn wa.
Emi ni wọn kọkọ waa sọ fun laaarọ ọjọ naa nipa ohun to ṣẹlẹ, ti mo si sọ fun wọn ki wọn lọọ wa ọmọ ọlọmọ nibikibi to ba wa, ibẹru boya Wolii le binu sọrọ si awọn olukọ ewe to n tọju wọn ni wọn ko fi tete jẹ ki wọn gbọ nipa rẹ, ti wọn si n wa gbogbo agbegbe to yi ile-ijọsin wa ka titi ti ọṣan fi pọn.
Iya ọmọ ni aago mọkanla ku isẹju mẹẹẹdọgbọn loun gbe ọmọ wa, o ni aago mejila ku iṣẹju mẹẹẹdogun lọmọ di awati, ohun to waa n ya mi lẹnu ni bo ṣe mọ igba to gbọmọ wa ati akoko gan-an ti ọmọ sọnu, ohun to yẹ kawọn eeyan beere lọwọ rẹ ni pe, ṣe o ti mọ pe iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ lọjọ naa lo ṣe ha gbogbo akoko naa sori?
ALAROYE: Ohun ta a gbọ ni pe ọpọ igba niru iṣẹlẹ bẹẹ maa n waye ninu ijọ yin?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Irọ ni wọn pa, iru eyi ko ṣẹlẹ ri lati bii ọdun mẹtala ta a ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ ijọ Sọtitobirẹ, kayeefi lọrọ ọhun jẹ fun wa, kẹ ẹ si maa wo o, Dadi wa sa gbogbo ipa to wa ni ikawọ wọn lori ati wa ọmọ naa. Loju ẹsẹ ti wọn gbọ nipa rẹ ni wọn ti pe awọn ọlọpaa lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn, ṣugbọn ṣe lawọn obi ọmọdekunrin naa sa lọ, ti wọn ko yọju mọ, koda, inu ṣọọsi lawọn atawọn oṣiṣẹ wọn sun mọju ọjọ keji ti wọn n sọna, ti wọon si n gbadura, boya wọn ṣi le rọmọ to sọnu yii pada.
Lọjọ keji, wọn tun gbiyanju ati ba iya ọmọ sọrọ lori foonu, wọn bẹ ẹ ko yọju si awọn ki awọn le jọ jiroro, ṣugbọn ṣe ni wọn tun kọ ti wọn ko yọju, ohun ta a ri lẹyin eyi ni pe wọn ko awọn tọọgi kan wa lati waa da sọọsi ru, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to tu wọn ka lọjọ naa ti wọn ko fi ri ṣọọsi jo, wọn tun pada wa lọjọ kẹta ti i ṣe ọjọ Isẹgun, Tusidee, ti awọn ẹsọ alaabo tun tu wọn ka, afi bii igba ti wọn ti ni wa sinu tẹlẹ.
Ohun ta a wa n gbọ lẹyin eyi ni oriṣiiriṣii ariwo to n lọ nigboro pe Wolii Ṣọtitobirẹ lo ji awọn lọmọ gbe, nnkan tọkọ mi ṣe fun wọn ti wọn fi koriira rẹ to bẹẹ ni ko ye mi.
ALAROYE: Nigba tẹ ẹ ni ṣe ni wọn koriira wọn, ki lẹyin ro pe o mu kawọn eeyan koriira ọkọ yin?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Ko ma ye mi o, boya nitori ootọ ọrọ to maa n sọ nitori pe ọkọ mi ki i parọ, bẹẹ ko ba wọn lọwọ si nnkan abuku lati igba to ti gba iṣẹ iranṣẹ, ki i ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni nigba tawọn eeyan ba fẹẹ ri i, igba to ba kan onitọhun ni yoo too gba a laaye ko wọle, lara idi tawọn kan fi lo n gberaga ree.
ALAROYE: Ibaṣepọ wo lo wa laarin Wolii Sọtitobirẹ ati ẹgbẹ Onigbagbọ ẹka tipinlẹ Ondo.
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Wọn o lọrẹẹ kankan laarin awọn iranṣẹ Ọlọrun, jẹẹjẹ wọn ni wọn n lọ, iwa buruku to wọpọ laarin awọn ti wọn n pe ara wọn ni iranṣẹ Ọlọrun ni wọn ṣe n sa fun wọn, ni ti ẹgbẹ awọn Onigbagbọ, ki i sọrọ afojudi ni wọn ko fi darapọ mọ wọ, awa o ri i gbọ pe wọn n ṣe ẹgbẹ kan, ohun ta a ro ni pe ti ijọ ba ti forukọ silẹ lọdọ ijọba, abuṣe buṣe, emi ro pe awọn ẹgbẹ CAN lo yẹ ki wọn nawọ ifẹ, ki wọn si waa ba wa lati ṣi wa niye idi to fi yẹ ka darapọ mọ wọn.
Lọna keji, akololo ni wọn, ẹyin naa mọ pe ọrọ sisọ maa n ni akololo lara, eyi wa lara idi ti wọn ki i fi i sọrọ pupọ.
ALAROYE: Ṣe loootọ lẹ ni ki wọn ti iya baba ọmọ to sọnu ati awọn eeyan rẹ mọle latari pe wọn fẹhonu han?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Ahesọ lasan ni, ko ri bẹẹ rara, ta ni nnkan rẹ fẹẹ sọnu ti ko ni i tara ka ma ti i sọ ti odidi ọmọ, ni kete ti Wolii gbọ pe wọn mu wọn ni wọn ti da si i, awọn gan-an wa lara awọn to ba awọn ọlọpaa sọrọ ti wọn fi tete yọnda wọn.
ALAROYE: Gẹgẹ bii olori ijọ, awọn igbesẹ wo lẹ gbe nigba tẹ ẹ gbọ pe ọmọ sọnu ninu ṣọọsi yin?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: A ni awọn ọlọpaa to n ṣọ wa lasiko ti ijọsin ba n lọ lọwọ, awọn ẹsọ alaabo ọhun si wa nitosi lasiko ti wọn lọmọ naa sọnu, ni kete ti Wolii gbọ ni wọn ti pe awọn ọlọpaa ni teṣan wọn lati fohun to ṣẹlẹ to wọn leti, wọn ṣeto adura ati aawẹ, bẹẹ ni wọn tun fun awọn ileeṣẹ redio kan lowo fun ikede, lẹyin-o-rẹyin lawọn funra wọn tun ko gbogbo awọn olukọ ewe to wa ni ṣọọṣi lọjọ naa lẹyin lọ si teṣan, nibi ti wọn ti fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Awọn ọlọpaa gba gbogbo foonu to wa lọwọ awọn oṣiṣẹ, bẹẹ ni wọn tun gba mejeeji to jẹ ti ọkọ mi fun ayẹwo finnifinni, ṣugbọn ti wọn ko ri ohunkohun to mu ifura lọwọ nipa ọmọ to sọnu.
Lẹyin ti wọn ti gbiyanju bii igba meji lati dana sun ṣọọsi, ṣugbọn ti wọn ko ri i ṣe la ṣẹṣẹ ba awọn ọlọpaa sọrọ lati waa maa ṣọ wa laimọ pe wọn aa si pada mu ifẹ inu wọn sẹ.
Aarọ ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun 2019, ni Wolii sọ fun mi pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ranṣẹ pe awọn, tayọtayọ ni wọn fi kuro nile nitori pe ṣe la ro pe wọn ti ba wa ri ọmọ tabi wọn fẹẹ ran wa lọwọ lori ọna ta a le fi ri i.
Iyalẹnu lo jẹ fun mi lọsan-an ọjọ naa nigba ti mo deedee ri ọpọlọpọ ọkọ ti wọn tẹle ara wọn wa sile wa, ọkọ mi lo kọkọ sọrọ, to ni awọn ọtẹlẹlẹmuyẹ lawọn fẹẹ waa yẹ ile wa wo, mo kọkọ fẹẹ beere lọwọ wọn ohun to pa ile wa pọ pẹlu ọmọ ti wọn n wa, ṣugbọn nigba ti ko ṣẹbọ lẹru wa, ti a ko si lohun ta a gbe pamọ sile yatọ si aṣọ atawọn dukia ta a ni, mi o wulẹ ba wọn jiyan mọ titi ti wọn fi wọle, ti wọn si bẹrẹ ohun ti wọn waa ṣe.
Ko sohun ti wọn ko tu tan nile wa lọjọ naa, wọn tu rọba, wọn tu kọnbọọdu aṣọ, koda, wọn tun tu gbogbo pata ati kọmu mi nibi ti wọn tule de, mi o mohun ti wọn n wa to bẹẹ, wọn ko tilẹ tiju pe kinni obinrin lawọn n tu, wọn gun oke ile wa, wọn wo abẹ bẹẹdi, wọn ko ri ohunkohun mu jade ju pasipọọti emi atawọn ọmọ mi, foonu ati kọmputa agbeletan, lẹyin ti wọn ṣetan ni wọn fi da mi loju pe ọkọ mi ko ni i pẹ pada wale ti awọn ba ti de ọfiisi awọn.
Nigba to di nnkan bii aago meje alẹ ti mi o ri i ko pada wale ni mo lọ sọfiisi wọn pe ki n wa wọn lọ nitori pe inu aawẹ ni wọn wa lọjọ naa, lori ọrọ ọmọ yii kan naa si ni. Nigba ti mo fẹẹ wọnu ọgba wọn ni mo pade lọọya rẹ ati aburo mi, awọn ni wọn sọ fun mi pe wọn ti fidi ọkọ mi gunlẹ sọdọ wọn, awọn foonu rẹ nikan ni wọn gba ki wọn ko jade ninu ọkọ to gbe lọ.
O to bii ọsẹ meji ki wọn too gba ki n ri wọn, aanu abiamọ si ṣe mi nigba ti mo ri i, abi bawo leeyan ṣe n jiya lori ohun ti ko mọwọ mẹsẹ rẹ, nibẹ ni mo ti gbọ pe wọn daku, ti wọn si gbe wọn lọ sile-iwosan lai jẹ ki n mọ.
Lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, la deedee gbọ iroyin pe wọn ni Wolii ti jẹwọ lọfiisi awọn ọtẹlẹmuya to wa, wọn ni wọn ti ri ọmọ ti wọn n wa lori pẹpẹ, gbogbo ahesọ tawọn eeyan kan gbọ ree ti wọn fi lọọ dana sun ṣọọṣi wa laaarọ ọjọ naa.
Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko si ẹri kan teeyan le ri di mu ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ, ki wa nidii ti iru idajọ bẹẹ fi tọ si i.
ALAROYE: Wọn lẹjọ ko gbọdọ jẹ ẹjọ ara ẹni ka ma mọ- ọn da, bi ejo ko ba lọwọ ninu bawo lọmọ ṣe fẹẹ sọnu laarin awọn alaboojuto mẹrinla ti wọn ko ni i mọ si i?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Loootọ ni, awọn mẹrinla ni olukọ ewe ta a ni, ṣugbọn oju kan naa kọ ni gbogbo wọn wa, bi awọn ọmọ naa ṣe dagba si la fi pin wọn, ko pọn dandan fun obi ki wọn gbe ọmọ wọn lọ sibẹ. Ninu alaye tawọn olukọ to wa nibi tọmọ ti sọnu ṣe, awọn meji ni wọn ni wọn gbe ọmọ naa wa laaarọ ọjọ naa ti wọn ko si mọ iyatọ laarin wọn, wọn ni lẹyin-o-rẹyin lọkan ninu wọn pada wa lati waa gbe ọmọ.
ALAROYE: Bawo lawọn olukọ ṣe n mọ awọn obi ọmọ kọọkan yatọ nigba ti wọn ba pada waa gbe wọn nigba tẹ ẹ lawọn ọmọ ti wọn n gbe wa pọ?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Wọn maa n mọ wọn daadaa, ko sẹni to ṣi ọmọ ọlọmọ gbe ri lati igba ta a ti n ko wọn sibẹ.
ALAROYE: Ki lero yin nipa idajọ ti wọn fun ọkọ yin?
IYAWO SỌTITOBIRẸ: Mo ṣi n tẹnu mọ ọn pe iya aimọdi lọkọ mi n jẹ, ọdun 2006 ni mo ti mọ wọn, bo tilẹ jẹ pe ọdun 2008 la too fẹra sile gẹgẹ bii ọkọ ati aya, iṣẹ ihinrere nikan lo gbaju mọ, ko mọwọ ọ yipada rara. Ṣe asiko yii t’Ọlọrun ti gbọ adura wa ni yoo ṣẹṣẹ waa maa ṣohun ti ko ṣe nigba ti iya n jẹ wa loju mejeeji, odidi ọmọ lo ti ku mọ mi lọwọ ri nitori ẹgbẹrun marun-un pere ti a ko ri fi gba ẹjẹ fun un nileewosan.
A ki i ṣẹbọ, bẹẹ la o ṣoogun, ta a ba si rọmọ ijọ ti Wolii ti fun ni nnkan dudu ri, o yẹ ki wọn jade waa sọ fawọn eeyan.
Ẹyin naa ẹ wo bi wọn ṣe ran ẹni ẹlẹni lẹwọn lẹyin ti wọn ti ba gbogbo dukia rẹ jẹ lori nnkan ọran ti ko da.
Mo bẹ gbogbo awọn agba wolii, awọn iranṣẹ Ọlọrun ati ẹgbẹ CAN ki wọn ba wa fẹmi wadii ododo iṣẹlẹ yii, mi o fẹ ki wọn ro aṣiṣe wa, adura ni ki wọn si fi ran wa lọwọ ki asiri ibi tọmọ naa wa le tu sita.
Bakan naa ni mo tun n bẹ gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ki wọn ba wa da si i, ọpọlọpọ igbesẹ ni mo ti gbe lati ri wọn, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun mi.