Oloye Ayọade Akande, ẹni ti ṣe Agba Oye ilu Ibadan ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77).
Ọjọ Abamẹta, Satide, ni ọkunrin olowo yii jade laye lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e.
Ninu atẹjade ti ọmọ ẹ ọkunrin, Olumide Akande, fi sita lo ti fidi ẹ mulẹ pe aisan ranpẹ lo ṣe baba naa to fi jade laye.
O ni, “Oniṣowo nla ni Oloye Harry Akande nigba aye ẹ, bẹẹ lo laami laka kaakiri, ti iṣẹ ati okoowo ẹ si fi i han gẹgẹ bii ojulowo eeyan gidi lagbaaye. Ti a ba n sọ nipa ala rere to ni fun ọjọ iwaju Naijiria, ko lẹgbẹ, bẹẹ lo nifẹẹ si ilọsiwaju orilẹ-ede yii daadaa. Ireti wa ni pe gbogbo ohun daradara to gba lero yii yoo wa si imuṣe laipẹ ̀ọjọ.”
Ọlumide fi kun ọrọ ẹ pe ojiji ni iroyin iku ẹ yii ba awọn mọlẹbi, ati pe niṣe lo ṣi n ṣe ọpọ bii ala.