Ọlawale Ajao, Ibadan
Idajọ oju ẹsẹ ni wọn ṣe fun ọmọkunrin ole kan nigboro Ibadan, niṣe ni wọn lu u pa, ti wọn si dana sun oku ẹ guruguru.
Ọkunrin ti ẹnikẹni ko mọ orukọ ẹ yii pẹlu ọrẹ ẹ kan la gbọ pe wọn jọ fipa ja maṣiini gba lọwọ ọlọkada kan laduugbo Olomi, n’Ibadan, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ti wọn si na papa bora.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lati adugbo Olomi yii lawọn eeyan ti fi ọlọkada le wọn de adugbo Ring Road, n’Ibadan. Lorita ti wọn n pe ni 110, laduugbo naa, lawọn ẹruuku ti le wọn ba, ṣugbọn ti ori ko ọkan ninu wọn yọ pẹlu bo ṣe ribi sa lọ patapata.
Ọkan ti ọwọ ba ninu wọn wọn, niṣe ni wọn lu u pa, ti wọn ko taya ọkọ bọ ọ lọrun, ti wọn si dana sun un si orita 110 nibẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti awọn ọdọ ọlọkada gbe naa, o ni bi wọn ṣe ṣe idajọ lọwọ ara wọn ko daa rara.
“Ti ọwọ araalu ba tẹ ẹnikẹni fun ẹsun ọdaran kan, ko tọ fun wọn lati fiya jẹ ẹ funra wọn, o yẹ ki wọn fa iru afurasi ọdaran bẹẹ le ọlọpaa lọwọ fun iwadii ati ijiya to ba tọ si i lọna ofin ni.” Bẹẹ ni SP Fadeyi sọ.
Iru Idaho owo bayi ko darato bee Ni won se Dana sun enikan naa niiyana lodge Lana