Tirela gba ọna ọlọna n’Ijẹbu-Ode, lo ba tẹ ẹni kan pa

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹjọ ku ogun iṣẹju aarọ ọjọ Aiku, Sannde akọkọ ninu oṣu Disẹmba yii ni tirela Volvo kan to fi oju ọna ẹ silẹ, to n gba ọna ọlọna n’Ijẹbu-Ode, da ijamba ọkọ silẹ, ti ẹni kan si doloogbe loju ẹsẹ.

Agbegbe Mobalufọn, niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, ṣe ṣalaye.

O ni loju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin lawọn ọkọ mẹta tiṣẹlẹ yii kan wa, awọn ọkọ naa ni tirela kan to gbe epo diisu, tirela Volvo to da wahala silẹ ati ọkọ ayọkẹlẹ Totoya kan.

Akinbiyi tẹsiwaju pe Volvo ti nọmba ẹ jẹ APP-595 XW, n bọ lati Ijẹbu-Ode ni, nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ Toyota ti nọmba tiẹ jẹ EKY -471 BR n bọ lati Benin, o si n lọ si Eko ni tiẹ. Oju opo to yẹ ko gba lo wa, Volvo lo fi ọna tiẹ silẹ, to lọọ doju kọ Toyota, bẹẹ ere buruku ni tirela Volvo yii tun n sa, bo ṣe padanu ijanu ẹ ni tirela to gbe diisu ko ri ọgbọn mi-in da, nitori oun lo wa lẹyin Toyota. Bi tirela onidiisu ṣe fẹgbẹ lelẹ niyẹn, ti gbogbo epo inu ẹ danu, ṣugbọn ko gbina.

Ọkọ Toyota ayọkẹlẹ lo fara gba wahala naa, nitori oun ni tirela Volvo doju kọ, ẹsẹkẹsẹ ni ẹni kan to wa ninu ọkọ naa ku, ti awọn ẹṣọ alaabo si gbe oku ẹ lọ si ile igbokuu-si Ijẹbu-Ode.

Ko sohun to ṣe dẹrẹba Volvo to fa ijamba yii, ọmọ ẹyin ọkọ rẹ paapaa ko fara pa. Ẹsẹkẹsẹ lawọn ọlọpaa ti mu awọn mejeeji, wọn ko wọn lọ si teṣan ọlọpaa Igbeba, n’Ijẹbu-Ode.

Leave a Reply