E sọ fun Buhari ko fura o
Ko si ijọba ti aburu le ba laye yii ti yoo ju ijọba to ba ni iru awọn eeyan mẹta yii ninu iṣejọba rẹ lọ, ijọba to ba ni Lai Muhammed, to ni Garba Sheu ati Fẹmi Adeṣina, ti awọn mẹtẹẹtaa si papọ lẹẹkan naa, ti wọn jọ n ṣejọba. Awọn mẹtẹẹta to lati ti iru ijọba bẹẹ ṣubu. Wọn yoo ti ijọba naa ṣubu nitori wọn yoo sọ iru ijọba bẹẹ di ọta araalu ni. Awọn ti wọn yoo ri dudu ti wọn yoo ni pupa ni, awọn ti ọga wọn yoo fẹẹ rin nihooho wọja, ti wọn yoo si maa sọ fun un pe aṣọ alarabara olowo nla lo wọ sọrun, awọn ti ọga wọn yoo fẹẹ wọ inu ina lọ bayii, ti wọn yoo ni ko ṣọra fun otutu lọna ibẹun. Tabi ẹ ko gbọ ọrọ ti Garba Shehu sọ nipa awọn agbẹ ti awọn Boko Haram lọọ dumbu mọ inu oko wọn ni. Ọkunrin naa ni wọn ko gba aṣẹ ki wọn too lọọ maa ja irẹsi loko naa, pe to ba jẹ wọn gbaṣẹ ni, iku oro bẹẹ ko ni i pa wọn. Aṣẹ nitori kin ni! Aṣẹ ki eeyan too lọọ ṣiṣẹ ninu oko rẹ! Loootọ, o ṣee ṣe ko jẹ adugbo ti awọn eeyan yii ti lọọ ṣiṣẹ oko wọn ko dara, ko jẹ ibi ti awọn Boko Haram sa pamọ si lati maa ṣiṣẹ ibi wọn niyi, to si yẹ ki gbogbo araalu jinna si agbegbe bẹẹ. Bi araalu ba gbọ alaye ati ọrọ gidi lẹnu awọn ti wọn n ṣejọba, awọn naa yoo mọ pe ọna iku ni, ọna ti ko dara ki awọn de rara ni. Ṣugbọn lori ọrọ Boko Haram yii, araalu wo ni yoo gbọrọ ti awọn Lai Muhammed, Garba Shehu yii ati Fẹmi Adeṣina yoo sọ lẹnu ti yoo jokoo sile. Tabi ki i ṣe awọn eeyan yii ni wọn n sọ fawọn araalu pe ko si Boko Haram nibi kan mọ, to jẹ ni gbogbo ọjọ ti wọn yoo ba sọrọ ni wọn yoo sọ pe Naijiria ti ṣẹgun wọn awọn ṣọja Naijiria ti le Boko Haram lọ, awọn ti wọn n sọrọ pe Boko Haram ṣi ku nibi kan, ọmọ PDP ni wọn, awọn ọta ijọba Buhari ni. Meloo meloo igba ni wọn ti sọ iru awọn ọrọ rauraru bayii, bawo ni araalu yoo waa ṣe mọ eyi ti wọn yoo gba pe Boko Haram ku sibi kan. Lara aburu ti awọn eeyan yii n ṣe niyẹn, to ba jẹ loootọ ni ibi kan wa ti awọn ara Borno ko gbọdọ de, a jẹ pe awọn Garba Shehu naa ni wọn ṣe iku pa awọn ti wọn ku yii nibi irọ ojoojumọ ti wọn n pa fun awọn eeyan naa pe Boko Haram ti lọ kuro lọdọ wọn. Bi ọrọ ba tilẹ waa ri bẹẹ, ewo ni ki eeyan kan lanu gbagada, ko kan maa fọntọ jade lasiko ti ọfọ iru bii iru eleyii ba ṣẹ. Ṣe dandan ni ki ọkunrin yii sọrọ ni! Ohun ti wọn n ṣe fun ijọba Buhari lẹ ri yii o, bi Buhari funra rẹ ko ba si fura, awọn ti yoo lu ijọba rẹ fọ niyẹn nibi irọ pipa ati isọkusọ. Ẹ sọ fun Buhari ko fura o, ifura loogun agba.
Awa kọ lọta yin, ẹyin gan-an lọta wa
Nigba ti eeyan ba gbọ bi awọn ọlọgbọn ori ni Naijiria ti n pariwo pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari le awọn olori ologun rẹ danu kuro ninu iṣẹ yii, tọhun yoo ro pe awọn araalu koriira awọn eeyan naa ni. Bi awọn olori ologun naa ba si n gbọ funra wọn, niṣe ni wọn yoo maa binu, ti wọn yoo ni awọn eeyan kan n binu nitori awọn fọ-nọtin ni. Ṣugbọn ootọ ọrọ ko ni i ni ka ma sọ oun o, awọn araalu ki i ṣe ọta awọn eeyan yii, awọn eeyan yiii gan-an lọta wa. Nigba ti eeyan ba fẹẹ wọ iṣẹ ijọba, agaga bo ba jẹ iṣẹ ologun, ofin ti wa nilẹ nibẹ. Ofin naa ni pe ti eeyan ba ti pe ọmọ ọgọta ọdun, o gbọdọ fi iṣẹ naa silẹ ni. Ti ko ba pe ọmọ ọgọta ọdun ree, to ba jẹ o ti fi ọdun marundinlogoji ṣe iṣẹ ologun yii, ko fi iṣẹ naa silẹ, ki awọn ẹlẹjẹ tuntun to ṣi lagbara, ti ọpọlọ wọn si le ṣiṣẹ kiakia, gba iṣẹ naa lọwọ wọn ni. Ṣugbọn ni Naijiria wa, Abayọmi Gabriel Ọlọniṣakin ni olori awọn ologun pata, ọdun 1981 lo si ti wọ iṣẹ ologun yii, iyẹn ni pe o ti lo ọdun mọkandinlogoji, o ti lo ọdun mẹrin tayọ iye ọdun to yẹ ko lo nibi iṣẹ yii. **Tukkur Buratai ni olori awọn ṣọja, oun ti le ni ọmọ ọgọta ọdun, bẹẹ lo si ti lo ọdun mẹtadinlogoji, o ti lo ọdun meji tayọ iye ọdun to yẹ ko lo ninu iṣẹ. Sadiq Abubakar ni olori awọn ọmọ ogun ofurufu, oun naa ti le ni ọmọ ọgọta ọdun, bẹẹ lo ti lo ọdun mọkanlelogoji lẹnu iṣẹ yii, ọdun mẹfa lo ti fi le si iye ọdun to yẹ ko lo. Ni ti olori awọn ọmọ ogun oju omi, Ibok-Ete Ekwe, oun paapaa ti le ni ọmọ ọgọta ọdun, ọdun mẹtadinlogoji lo si ti lo lẹnu iṣẹ yii, iyẹn ni pe oun naa ti lo ọdun meji tayọ iye ọdun to yẹ ko lo. Lọrọ kan, ko si ẹni kan bayii ti ko ti i kọja aaye ara rẹ ninu awọn olori ologun wa. Eeyan ko le ta ọja erupẹ, ko ma gba owo okuta, bi a ba ṣe e bo ti yẹ ka ṣe e nikan ni yoo ri bo ti yẹ ko ri. Ijọba Buhari ko ṣe e bi wọn ti n ṣe e, tabi kin ni awọn olori ologun wọnyi ṣi n wa lẹnu iṣẹ ijọba. O ti rẹ wọn! Iṣẹ naa ti su wọn! Apa wọn ko ka nnkan kan mọ! Eeyan ko si le bu wọn, nitori wọn ti ṣe iwọnba ti wọn le ṣe, wọn ti ṣe iṣẹ kọja akoko wọn. Bo ya wọn fẹẹ lọ tabi wọn ko fẹẹ lọ, ko si idi ti olori ijọba ko fi gbọdọ sọ pe wọn ṣeun, ki wọn waa maa lọ. Ṣugbọn tiwa ko ri bẹẹ, niṣe la ko awọn ẹgẹrẹmiti eeyan jọ ti a ni awọn ni olori ologun. Ko daa bayii o, eleyii ko daa o! Kin ni Boko Haram ko ni i fiya jẹ wa si, nigba ti awọn olori ologun wa ti darugbo! Ẹẹ le pa wa o, Ọlọrun yoo gba wa lọwọ yin!
Ni ti SARS ati wọn ti wọn yinbọn fun
O yẹ ki awọn olori ologun, ati ọlọpaa ati ṣọja, pẹlu awọn ti wọn n ṣejọba wa dawọ boju fun ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii ni. Niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ ohun to ṣẹlẹ ni ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, nibi ti awọn ṣọja ti yinbọn lu awọn ti wọn n ṣe iwọde SARS ni too-geeti ni Lẹkki, odidi bọọsi kan ni wọn fi ru awọn eeyan ti wọn fara pa wa. Wọn ko wọn wa, wọn si fẹrẹ le ni ogun, ko si si ẹni ti ko ni iroyin buruku kan lati sọ ni ọjọ naa. Idi ni pe awọn to ti ge lẹsẹ ti ge lẹsẹ, awọn ti wọn de ni bandeeji lagbari wa nibẹ ti wọn n gbin kẹn-ẹn, awọn ti ibọn si ti jẹ nifun danu wa ninu wọn. Koko ohun ti wọn ba wa naa ni pe awọn ki i ṣe alaabọ ara ko too di ọjọ iṣẹlẹ naa, nibi iṣẹlẹ naa lawọn ṣọja ti yinbọn lu awọn. Lojoojumọ lawọn ṣọja n sọ pe awọn ko yinbọn, ti wọn ni ere lawọn lọọ ba awọn ti wọn n ṣe iwọde naa ṣe, awọn kan lọ sibẹ lati ra miniraaasi ati bisikiiti fun wọn ni, bẹẹ lawọn eeyan ijọba naa n sọ pe ko si ṣọja to yinbọn. Ṣugbọn lojoojumọ ni aṣiri awọn eeyan yii n tu, ti wọn si n di oniyẹyẹ loju aye, nitori loootọ ni wọn kuku yinbọn, loootọ ni wọn paayan, gbogbo agbaye si ti ri irọ wọn ti wọn n pa. Bi eniyan ba hu iwa kan to buru, tabi to ba ṣẹ ẹṣẹ kan ti ko dara, ohun kan ṣoṣo to le ṣe lati fi ri idariji naa ni ko tuuba, ko jẹwọ ẹṣẹ rẹ ni gbangba, ko si tọrọ aforiji. Ẹni to ba ṣe aṣiṣe to jade, to bẹ awọn to ṣe e fun, ohun ti eleyii fi han ni pe tọhun ti mọ pe ohun ti oun ṣe ko dara, ko si ni i ṣe iru rẹ mọ nibi kan. Ṣugbọn ẹni to ṣe aṣiṣẹ to ta ku pe oun ko ṣe aṣiṣe, tabi to n purọ pe oun ko si nibẹ, itumọ eyi ni pe tọhun yoo ṣe eyi to buru ju bẹẹ lọ lọjọ iwaju. Ohun ti awọn ṣọja ati awọn ọlọpaa wa, pẹlu awọn eeyan ijọba n sọ ni pe awọn yoo tun paayan rẹpẹtẹ lọjọ mi-in, awọn yoo ṣe aburu to ju bayii lọ, lọjọ iwaju. Ṣugbọn aye ko ni i gba eleyii fun wọn, awọn ọmọ Naijiria paapaa ko ni i gba, ọrọ naa yoo si mu wọn lomi, yoo bọ ṣokoto nidii wọn paapaa lọjọ ti wọn ba tun dan iru rẹ wo nibi kan. Ijọba, ẹyin ṣọja, ẹ jade kẹ ẹ jẹwọ ẹṣẹ yin, ẹ jẹwọ ni gbangba pẹyin lẹ yinbọn paayan ni Lẹkki, awọn ọmọ Naijiria yoo fori ji yin, ẹyin naa yoo si le ri iyọnu Ọlọrun. Ṣugbọn bi ẹ ba n purọ bayii kiri o, ẹni to ba n pa iru irọ bayii yoo ri ibinu awọn eeyan, koda, yoo ri ibinu Ọlọrun Ọba!
Ole buruku lawọn eeyan yii o
Bi eeyan ba n ṣiṣẹ fun ijọba, awọn owo kan wa ti wọn maa n tọju fun wọn. Loṣooṣu ni wọn yoo maa yọ owo yii pamọ ninu owo-oṣu wọn. Owo yii ni wọn maa n pada fi san owo ifẹyinti fun wọn nigba ti wọn ba kuro nibi iṣẹ ijọba, ti wọn si ti fẹyin ti. Owo yii ni wọn n pe ni pẹnṣan (pension), owo ti awọn to ba ti ṣiṣẹ tan yoo gba titi ikẹyin aye wọn ni. Bi oṣiṣẹ kan ba ṣiṣẹ tan, ko si ijọba nibikibi to lẹtọọ lati fi iru owo bayii jẹ awọn oṣiṣẹ niya nigba to jẹ owo wọn ni, oogun wọn ni, owo ti ijọba ti fi bii ọdun marundinlogoji yọ lowo wọn ni. Ṣugbọn iroyin to n jade lati ileeṣẹ to n tọju owo pẹnṣan yii pamọ ko dara. Iroyin naa ni pe ijọba Buhari ti ya owo rẹpẹtẹ ninu owo awọn eeyan yii, wọn si ti na an. Ni ọdun 2018, owo to wa ninu apo ikowopamọ pẹnṣan si jẹ tiriliọnu mẹjọ, owo rẹpẹtẹ gbaa ni. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di asiko ti a wa yii, ijọba Buhari yii ti ya tiriliọnu mẹfa kuro nibẹ, n lowo ko ba pe tiriliọnu meji daadaa mọ. Idi eyi lo fa a ti ẹ fi maa n ri awọn oṣiṣẹ-fẹyinti, ti wọn yoo to si ileeṣẹ ijọba lati aarọ ṣulẹ, ti awọn mi-in yoo ku sibẹ, ti iya buruku yoo maa jẹ awọn mi-in pẹlu ẹbi wọn, nitori ti ijọba ko san owo ifẹyinti wọn fun wọn. Iya yoo si jẹ ẹlomi-in titi ti yoo fi ku nitori pe o ṣiṣẹ fun ijọba ilẹ wa. Oogun alaaaru ki i gbẹ, iru awọn owo bayii ki i ṣe owo ti ijọba kan n ya, nitori ijọba kuku n fi owo awọn eeyan yii ṣowo lati ọjọ yii wa ni. Bi wọn ti n yọ owo yii lọwọ wọn ni wọn n fi n ṣe owo nla nla, ti wọn si n jere nibẹ, ki waa lo de ti wọn ko ni i ko owo fawọn ti wọn ni in to ba ya. Awọn yii ni wọn n kọ awọn oṣiṣẹ ijọba lole, nigba ti oṣiṣẹ kan ba ti mọ pe ti oun ba ti kuro nijọba, oun ko ni i ri owo ifẹyinti oun gba mọ, ki lo de tiru oṣiṣẹ bẹẹ ko ni i ko gbogbo owo to ba le ko jẹ jẹ laarin igba to ba fi n ṣe iṣẹ ijọba. Ati paapaa, iru awọn iwa bayii a maa fa ibinu Ọlọrun, nigba ti ẹ ko ba fun ẹni to ṣiṣẹ lowo iṣẹ to ṣe. Ta lo tiẹ mọ boya lara epe to n ja wa ni Naijiria ree, ti gbogbo nnkan wa fi n di rudurudu. Ẹ da owo tẹ ẹ ya yii pada kia, kẹ ẹ si san owo awọn oṣiṣẹ-fẹyiti fun wọn. Ẹ ma fiya jẹ awọn agba oṣiṣẹ yii mọ, ẹ ṣanwo folowo.
Ṣebi ẹyin naa n gburoo Maina, ogbologboo ọdaran
Owo awọn onipẹnṣan yii loun naa ko jẹ nigba to fi jẹ olori ileeṣẹ naa. Abdul Rasheed Maina, oun ni ọga ileeṣẹ to n ṣeto owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ nigba kan. Nigba ti oun fi wa nibẹ, niṣe lo n ko owo nla nla jẹ, o si ko owo naa jẹ titi debii pe apo owo naa gbẹ. N ni wọn ba mu un pe wọn yoo ba a ṣejọ, n lawọn ara ilẹ Hausa bii tirẹ ba dide, ni Sẹnetọ kan, Ali Ndume ba gba beeli rẹ pe ko le sa lọ. Bi Maina ti jade bayii, orileede Nijee lo sa lọ, ṣe o ti kọle sibẹ, o si tun ra ile si Amẹrika kaakiri. Owo pẹnṣan yii naa lo fi n ṣe e o! N ni wọn ba wa a ti o, nitori ko pada wa si Naijiria mọ. Nigba ti adajọ ko ri i mọ, lo ba ni ki wọn mu Ndume to duro fun un, ni wọn ba ti oun mọle, kia ni Maina jade. Awọn ọlọpaa agbaye lo gbe e lati Nijee, ni Ndume ba loun o le duro fun un mọ, n ladajọ ba ni yoo wa lẹwọn titi ti wọn yoo fi dajọ ẹ ni. Ohun ti wọn n fi owo wa ṣe niyẹn, O ji owo ko ni Naijiria, o fi kọle si Nijee, nigba ti aṣiri tu, o sa lọ sibẹ tọmọ-tọmọ. Ṣugbọn ọwọ ti tẹ ẹ bayii, ninu itimọle nibẹ ni yoo wa titi, koda bo jẹ ọdun marun-un ni ẹjọ rẹ too pari. Tabi ki la kuku ṣe fawọn eeyan wọnyi ti wọn n fi aye ni wa lara bayii! Ọlọrun yoo mu yin o, gbogbo ẹyin ti ẹ n ji owo Naijiria ko lọ si Nijee, ti ẹ fi iwa buruku yin daamu awọn ọmọ Naijiria, Ọlọrun yoo daamu ẹyin naa daadaa.