Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ajalu mi-in tun ti ja lu idile Ọlawale lagbegbe Ọwa-Ọpẹ, niluu Gbọngan bayii, lẹyin oṣu mẹrin ti ọkan lara awọn ogo idile naa, Festus Ọlawale, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Pele Onikoko jade laye.
Iya to bi ọmọkunrin naa la gbọ pe oun naa ki aye pe o digbooṣe nibẹrẹ ọsẹ yii.
Iya naa, ẹni ti gbogbo awọn araalu mọ si iya elepo la gbọ pe o lọ sọja lati ta epo, latibẹ lo si ti bẹrẹ aisan, nigba ti yoo si fi to wakati kan, iya naa ti gbẹmi-in mi.
Oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni Pele Onikoko, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, pokunso sinu sọọbu to ti n ta koko lagbegbe Oke-Ọla, niluu Gbọngan, ti ko si sẹni to mọ idi to fi ṣe bẹẹ.
Gẹgẹ bi ẹnikan niluu Gbọngan to ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiri ṣe sọ, o ni latigba ti Festus ti ku ni iya rẹ ko ti bọ sipo, o si ṣee ṣe ko jẹ ironu iku rẹ lo tete ran iya rẹ sọrun aremabọ.