Jẹmila to dana sun obinrin ẹgbẹ ẹ mọle lọjọsi ti dero ọgba ẹwọn

Faith Adebọla, Eko

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ọdun mọkandinlogun pere ni Jẹmila Ibraheem, to si tun jẹ obinrin, sibẹ, ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa l’Ọgba, nipinlẹ Eko, ti paṣẹ lowurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, pe ki wọn sọ ọ sọgba ẹwọn to wa ni Kirikiri, latari ẹsun pe o dana sun ile afẹsọna ẹ tẹlẹ, Mohammed Yusuf, to si ṣe bẹẹ sun ọmọbinrin tiyẹn ṣẹṣẹ n fẹ, Rabi, mọle.

Agbefọba, to ṣoju fun olupẹjọ, Thomas Nurudeen, sọ pe ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, to kọja yii, niṣẹlẹ buruku naa waye l’Opopona Ekoba, Monkey Village, Satelite Town, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni iwadii tawọn ọlọpaa ṣe fihan pe afurasi ọdaran yii lọ sile afẹsọna rẹ tẹlẹ laaarọ ọjọ ọhun, o si ba oloogbe naa nibẹ, eyi to mu ko ro pe ibẹ lọmọbinrin naa sun mọju, lo ba fa ibinu yọ.

Ko pẹ lẹyin naa lo pada wa oun ati ọrẹ rẹ mi-in pẹlu epo bẹntiroolu, o si dana sun ile naa lai bikita pe oloogbe naa wa ninu rẹ, iṣẹlẹ naa lo si ṣeku pa Rabi lẹyin wakati diẹ tawọn alaaanu kan dọgbọn yọ ọ jade ninu ina, bo tilẹ je pe o ti fara pa gidigidi.

Ọjọ kẹta lẹyin eyi lọwọ tẹ Jẹmila ti wọn lo n kọṣẹ ere tiata  nibi to sapamọ si, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e, ti  iwadii si ti fihan pẹlu ẹri gidi pe oun lo mọ-ọn-mọ huwa ika naa,.

Nigba ti wọn ni ko fesi, niṣe ni olujẹjọ rawọ ẹbẹ si Adajọ P. E. Nwaka pe ki wọn ṣaanu oun, kile-ẹjọ jẹ koun maa ti ile waa jẹjọ, ṣugbọn adajọ wọgi le ẹbẹ rẹ, o waa paṣẹ pe ọgba ẹwọn Kirikiri ni ki wọn gbe e lọ, titi di ọjọ kẹrin, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ. O ni ki agbefọba tete gbe faili ẹjọ naa siwaju ajọ to n gba adajọ nimọran ki igbẹjọ to kan too waye.

 

Leave a Reply