Florence Babaṣọla, Osogbo
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelaaadọta kan, Bejide Ayọdele, lo ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lori ẹsun pe o ti iyawo ati ọmọ rẹ mọnu ile pẹlu agadagodo.
Agbefọba to gbe Ayọdele wa si kootu, Sajẹnti Saheed Anifowoṣe, ṣalaye fun kootu pe laaarin ọjọ kẹtadinlogun, si ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni
olujẹjọ ti iyawo rẹ, Mary Lawance, atawọn ọmọ rẹ; Ayọowurọ Bejide ati Tobilọba Bejide, mọnu ile lai jẹ ki ẹnikẹni ri wọn, bẹẹ lo si n dunkooko mọ ẹmi wọn nibẹ.
O ni olujẹjọ huwa to le da omi alaafia agbegbe ru, to si n halẹ wahala mọ awọn olupẹjọ. Awọn ẹsun naa lo sọ pe o ni ijiya labẹ abala ikọkanlelọgọrin ati aadọrun-in o din mẹrin ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Temitọpẹ Ọlajọlọ, bẹbẹ fun beeli rẹ lẹyin to sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan an.
Adajọ A. A. Adebayọ fun un ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) ati oniduuro kan to gbọdọ maa gbe lagbegbe ile-ẹjọ.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkanla, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.