Stephen Ajagbe, Ilorin
Ẹka to n gbogun ti iṣẹlẹ fayawọ nileeṣẹ aṣọbode lẹkun Aarin-Gbungbun orilẹ-ede Naijiria, North Central Joint Border Operations Drill (JBOD) ti gba ẹru ofin oriṣiriiṣii tiye rẹ jẹ miliọnu mẹtadinlaaadọfa naira (#107m) lọwọ awọn onifayawọ nipinlẹ Kwara atawọn ipinlẹ mi-in to wa lẹkun naa.
Ọga aṣọbode to n mojuto ẹka JBOD,
Ọgbẹni Olugboyega Peters, lo kede aṣeyọri ajọ naa laarin ọjọ mẹrinlelogun lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, niluu Ilọrin.
Olugboyega ni lara ohun tawọn ri gba lọwọ wọn ni apo irẹsi ilẹ okere to din diẹ lẹgbẹrun kan, ọkọ agbepo bẹntiroolu to gbe lita epo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn pẹlu kẹẹgi epo bẹntiroolu marundinlaaadọta.
Awọn nnkan mi-in ti wọn tun ri gba ni, paali aloku aṣọ oyinbo mọkanlelogun, kẹkẹ Maruwa meje, paali ọti taju-taju ati ọti mi-in mẹẹẹdọgbọn, ọkọ aloku mejila ati awọn ẹya ara ọkada pẹlu kẹkẹ Maruwa.
O ni awọn onifayawọ ti tun n ko irẹsi ilẹ okere ti wọn ko ti i bo eepo lara rẹ sinu apo nla wọle bayii, eyi to maa da bii ti ilẹ wa loju awọn agbofinro to ba da wọn duro.
O ni ọkọ tirela marun-un to ko iru irẹsi bẹẹ to le ni ẹgbẹrun kan apo, 1,677, lọwọ awọn tẹ lagbegbe Chikanda ati Okuta lẹkun Arewa Kwara tiye rẹ le ni miliọnu mejidinlogun naira, #18.4m.
O waa kilọ fun gbogbo awọn to n ṣowo tijọba ti fofin de lati jawọ kiakia nitori pe ajọ naa yoo tẹsiwaju lati maa gbogun ti iṣẹlẹ fayawọ ati ohun to le mu ifasẹyin ba ọrọ-aje orilẹ-ede Naijiria.