PDP ko ti i ni in lọkan lati lo Goodluck Jonathan gẹgẹ bii oludije wa-Secondus

Jide Alabi

Bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Goodluck Jonathan, ni ẹgbẹ oṣelu PDP fẹẹ lo lati dupo aarẹ lọdun 2023, alaga ẹgbẹ naa, Uche Secondus, ti sọ pe, ẹgbẹ ko ti i ni ẹnikankan lọkan rara.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, lo sọrọ yii fawọn oniroyin niluu Abuja gegẹ bii ileeṣe iroyin NAN ṣe fi iroyin ọhun sita.

Secondus sọ pe agbeyẹwo bii ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣe daadaa si lo ṣi n lọ lọwọ bayii fun ipalẹmọ ibo ọdun 2023.

O ni ni kete tawọn kuna lati wọle sipo aarẹ lọdun 2015, igbesẹ akọkọ ti ẹgbẹ naa gbe ni lati ṣewadii ohun to fa ijakulẹ wọn, ati pe nigba ti abajade ẹ jade, pẹlu ọna abayọ, eyi lo fa a ti ẹgbẹ naa fi ṣe daadaa ninu ibo 2019, ninu eyi ti wọn ti ni gomina mẹrindinlogun bayii, dipo mọkanla ti wọn ni lẹyin ibo 2015.

Ninu ọrọ ẹ naa lo tun ti sọ pe ẹgbẹ naa ko ti i pinnu boya Ariwa, lọdọ awọn Hausa lọhun-un, ni aarẹ yoo ti wa ni, tabi ni Guusu nisalẹ nibi. O fi kun un pe bi Aarẹ tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Goodluck Jonathan, ṣe lanfaani lati dije, bẹẹ lawọn mi-in naa ni in ninu ẹgbẹ ọhun.

Alaga yii ni ọrọ ibo 2023 kọ lo yẹ ki awọn eeyan maa sọ bayii, nitori ọjọ ọhun ṣi jinna, ati pe ohun to jẹ PDP logun bayii ni agbeyewọ ibi ti ọrọ awọn ku si, ki ijade awọn lọdun 2023 le kẹsẹ jari daadaa.

 

Leave a Reply