Wọn dana sun ole kan to ji ọkada n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdọ ti fibinu dana sun ole kan ti ọwọ wọn tẹ.

Aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ Aiku, Sannde, la gbọ pe ọmọkunrin naa ja ọkada kan gba lọwọ ẹni to ni i lagbegbe Oke-Ọgbọ, ni Ilode, niluu Ileefẹ, to si n gbe e sa lọ.

Bo ṣe n lọ lawọn ọlọkada tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sa tẹle e, nigba ti wọn si ri i mu, wọn lu u bii kiku, bii yiye ko too di pe wọn dana sun un mọbẹ.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe ki awọn ọlọpaa too debi iṣẹlẹ naa ni wọn ti dana sun wọn.

 Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ meji sẹyin ni wọn dana sun ole kan to ji ọkada gbe lagbegbe Lagere, niluu Ileefẹ yii kan naa, ti wọn si dana sun awọn afurasi ajinigbe meji niluu Iwo, lọsẹ to kọja.

 

Leave a Reply