Ijọba ti ko awọn ọlọpaa SWAT ti wọn fi rọpo SARS jade

Faith Adebọla, Eko

Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, IGP Mohammed Adamu, ti paṣẹ lojọ Aje, Mọnde, pe ki wọn da awọn ikọ ọlọpaa afọgbọn-jagun (Special Weapon and Tactical Team) SWAT, ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ jade kaakiri origun mẹrẹẹrin Naijiria sita lẹyẹ-o-sọka.

Ninu atẹjade kan ti Adamu kọ si gbogbo awọn Igbakeji Ọga Agba mẹtadinlogun atawọn kọmiṣanna ọlọpaa kaakiri awọn ipinlẹ lorileede yii lo ti paṣẹ naa.

 

O ni kawọn ikọ tuntun naa bẹrẹ iṣẹ ni gbogbo ipinlẹ ati agbegbe ti wọn ba pin wọn si, ki wọn le ro eto aabo lagbara, ki wọn si kun awọn ọlọpaa to wa nilẹ tẹlẹ lọwọ ninu ojuṣe wọn.

Tẹ o ba gbagbe, lasiko iwọde gbigbona janjan ta ko ikọ ọlọpaa SARS to waye loṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn ko ikọ SARS kuro nilẹ, ko si ju ọjọ meji lẹyin naa tijọba fi kede idasilẹ ikọ SWAT tuntun yii, gẹgẹ bii arọpo wọn.

Leave a Reply