Jide Alabi
Pẹlu gbogbo akitiyan agbẹjọro fun Wolii ijọ Sẹlẹ nni, Dele Ogundipẹ, tawọn eeyan tun mọ si Genesis, lati gba beeli rẹ, ko si kuro lọgba ẹwọn lati maa waa jẹjọ lati ile, pabo lọrọ ọhun tun ja si bayii.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Adajọ Ọlabisi Akinlade ti ile-ẹjọ giga kan l’Ekoo sọ pe oun ko ni i fun un ni beeli, eyi ti yoo fun un lanfaani lati maa waa jẹjọ latile, lori bi ọkunrin naa ṣe tun pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun bayii.
Ọrọ kan ti adajọ ọhun tẹnu mọ ni pe, ọgba ẹwọn Kirikiri ti wọn sọ Dele Genesis si naa ni ko maa gba waa jẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to ti pe bayii.
Ninu ẹbẹ ti agbofinro ẹ, Ọlanrewaju Ajanaku, n bẹ ile-ẹjọ ni pe, ki wọn fun un ni beeli, ko maa ti ile waa jẹjọ titi ti ile-ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to pe.
Genesis ninu iwe ẹbẹ ti agbẹjọro ẹ ko wa sile-ẹjọ sọ pe aisan itọ ṣuga n da oun laamu, eyi ti ko jẹ ko le maa tẹle alasilẹ ounjẹ ti o gb̀ọdọ maa jẹ, ati pe kinni ọhun ti n ṣakoba nla fun ilera rẹ.
Yatọ si eyi, wọn tun ni awọn aisan bii ẹjẹ riru ati ọgbẹ inu n da a laamu pẹlu, bẹẹ ni aisan iba paapaa ko jẹ ko gbadun, eyi to ti ṣakoba fun eto ilera ẹ lati ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, to ti wa lahaamọ ijọba lọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo.
Ṣugbọn ninu iwe ti agbẹjọro fun ijọba, Rotimi Odutọla, fi fesi si ẹbẹ Genesis lori beeli to n beere fun yii lo ti sọ pe niṣe ni ọkunrin naa n parọ, ati pe ile-ẹjọ ko gbọdọ fun un ni beeli kankan.
O ni ko sigba kan bayii ti Wolii Sẹlẹ yii sọ pe ailera kan n ba oun ja ni gbogbo igba ti ẹjọ ọhun fi n lọ lọwọ, ki wọn too ran an lẹwọn, O ni ohun iyalẹnu lo jẹ bo ṣe n parọ oriṣiiriṣii mọra ẹ bayii laarin ọsẹ mẹta pere to ṣẹṣẹ lo lọgba ẹwọn.
Loju-ẹsẹ naa ni Adajọ Akinlade ti sọ pe oun ko ni i fun Genesis ni beeli kankan, nitori ko ri idi kankan bayii fi mulẹ pe loootọ lawọn aisan ọhun n ṣe e, ati pe ko si akọsilẹ kankan lọsibitu ijọba to wa ninu ọgba ẹwọn to fidi ẹ mulẹ pe loootọ lo waa n gba itọju nibẹ rara.
Bakan naa lo sọ pe ọkunrin ti wọn sọ sẹwọn yii ko ni iwe-ẹri eto ilera kankan to sọ pe loootọ ni awọn aisan buruku ọhun n ba a finra. Fun idi eyi, ki Dele Genesis ṣi maa gbatẹgun ẹ nibẹ naa.
Lọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni Adajọ Ọlabisi Akinlade ju purọfẹẹti ijọ Sẹlẹ ọhun si ẹwọn, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe o sọ dukia onidukia di tara ẹ, bakan naa nile-ẹjọ tun pe e lole.