Alaga ẹgbẹ PDP l’Ekoo, Adedeji Doherty, kọwe fipo silẹ

Faith Adebọla, Eko

Ẹnjinnia Adedeji Doherty to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, nipinlẹ Eko, ti kọwe fipo naa silẹ, o loun o ṣe mọ.

Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni Alukoro ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Taofik Gani, fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin.

O ni ninu lẹta ikọwe-fipo-silẹ ti alaga naa kọ, ko sọ pe tori ohun kan tabi ẹni kan loun ṣe ṣepinnu naa, o kan ni oun funra oun lọrọ naa ye.

Amọ ṣa o, Gani ni aaye alaga naa ko le ṣofo, o ni igbakeji rẹ yoo bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii adele alaga titi ti igbimọ alakooso ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko ati ti apapọ yoo fi sọ igbesẹ to kan.

O tun ni ipade pẹlu awọn oniroyin yoo waye laipẹ lori ọrọ ọhun, nibẹ lawọn yoo ti ṣe ẹkunrẹrẹ alaye.

ALAROYE sapa lati ba Doherty sọrọ, ṣugbọn ipe rẹ ko wọle, ko si fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ṣowọ si i.

Leave a Reply