Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Oluṣeyi Makinde ti ṣọ pe o yẹ kawọn ọmọ Naijiria fura bayii pe Ọlọrun ti kọyin si ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ yii, iyẹn APC, o ni omi ti tan lẹyin ẹja wọn.
Atẹjade kan ti gomina naa fi sode lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP lati ẹkun Iwọ-Oorun l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, eyi to waye nile ijọba to wa l’Agodi, n’Ibadan, lo ti sọrọ naa pe gbogbo awọn ti wọn ti n polongo ibo silẹ de ọdun 2023, atawọn to ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ, ṣugbọn to jẹ ẹgbẹ APC yii ni wọn fẹẹ ba jade maa kabaamọ gbẹyin ni, tori ẹgbẹ t’Ọlọrun ti kọyin si ni.
Ọgbẹni Taiwo Adisa to jẹ Akọwe iroyin gomina lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to tẹ akọroyin wa lọwọ pe Ṣeyi Makinde ṣekilọ fawọn aṣaaju ẹgbẹ PDP ti wọn n jẹjọ lọdọ ajọ EFCC, ti wọn fẹẹ tori ẹ kuro lẹgbẹ ọhun pe ki wọn tun ero wọn pa.
O ni ẹwọn ti wọn n sa fun naa lẹgbẹ APC ṣi maa ran wọn tori bo ṣe ṣẹlẹ si gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ, Joshua Dariye, niyẹn, gomina ipinlẹ Taraba tẹlẹ, Rẹfurẹndi Jolly Nyame, titi kan tipinlẹ Abia igba kan, Orji Uzor Kalu, to ṣẹṣẹ jade lẹwọn laipẹ yii.
O ni arun oju ni bi iṣejọba APC ṣe ri, ko sẹni to wa lorileede yii ti ko mọ bi iṣakoso naa ṣe nira to.
Makinde waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ tinu n bi lati duro de igbimọ apẹtusaawọ ti Ọlagunsoye Oyinlọla ṣe alaga rẹ, ki wọn baa le ojutuu si ohunkohun to ba n bi wọn ninu. O lo da oun loju pe didun lọsan yoo so.