Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọrọ bẹyin yọ fawọn ikọ ajinigbe kan lọsẹ ta a wa yii pẹlu bawọn sọja bareke Ọwẹna, to wa l’Akurẹ, ṣe yinbọn pa ọkan ninu wọn, tawọn mi-in si tun fara gbọta nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ji awọn arinrinajo kan gbe loju ọna Ibilo si Isua Akoko.
Ọgagun Ọmọjokun to jẹ Alukoro awọn ologun bareke Ọwẹna fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ sawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe lasiko tawọn ikọ ajinigbe ẹlẹni mẹfa naa n gbiyanju ati ji awọn arinrinajo kan gbe labule Igara, lawọn apapọ ẹsọ alaabo ya lu wọn lojiji.
O ni bawọn janduku naa ṣe ri awọn ni wọn ti mura ija, bẹẹ lawọn agbebọn ọhun atawọn ẹsọ alaabo si bẹrẹ si i yinbọn sira wọn.
Ninu ijakadi yii ni wọn ti yinbọn pa ọkan ninu awọn ajinigbe ọhun, ti pupọ lara wọn si tun fara gbọta ki wọn too sa wọnu igbo lọ.
Mẹta ninu awọn ti wọn sẹsẹ ji gbe naa lo ni awọn ri gba pada pẹlu ọkọ jiipu Toyota Highlander kan ti nọmba rẹ jẹ, AKD 56 GS.
Awọn nnkan mi-in ti wọn tun gba pada lọjọ naa ni, owo to to bii ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun-un din mẹwaa Naira (#350, 000), ada nla kan, oogun Tramadol loriṣiirisii ati foonu ilewọ Itel kan.
Ọga sọja ọhun rọ araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo nipa titu asiiri ibuba awọn onisẹẹbi naa fun wọn.