Faith Adebọla, Eko
Ori lo ko awọn olugbe ile kan lagbegbe Ibẹju-Lẹkki, nipinlẹ Eko, yọ, diẹ lo ku ki afurasi adigunjale ẹni ogun ọdun kan, Lekan Razak, pitu ọwọ ẹ fun wọn.
ALAROYE gbọ pe ile kan to wa ni Ojule kẹẹẹdọgbọn, Opopona Ibomide, ni Ibẹju-Lẹkki, ni Lekan mura ati wọ, o mu ibọn ilewọ kan pẹlu awọn ọta ibọn ti wọn ko ti i yin dani.
Wọn ni bi afurasi naa ṣe n pooyi ayika ile ọhun, to n wa ọna to maa ba wọle lawọn aladuugbo kan ti wọn fura si irin to n rin ti dọgbọn tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago ni teṣan Akodo. Kia si lawọn yẹn ti wa sibẹ.
Ibi ti Lekan lugọ si lawọn ọlọpaa naa ka a mọ, bo ṣe ri wọn lo ki ere mọlẹ, ṣugbọn ko le sare ọhun debi kan ti okun tawọn agbofinro fi le e mu, wọn si ko ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun ALAROYE sọ pe funra ọmọkunrin naa lo jẹwọ pe ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ loun, oun n digunjale, ati pe ọna ati raaye wọle naa loun n ṣan lọwọ.
Gẹgẹ bi Hakeem Odumosu ṣe paṣẹ, wọn ti fi afurasi naa ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Eko fun iwadii to lọọrin.
Lẹyin iwadii ni wọn maa gbe afurasi ọdaran yii lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bi Adejọbi ṣe sọ.