Adefunke Adebiyi, Abeokuta
Ẹbẹ ti ẹgbẹ Onigbagbọ lorilẹ -ede yii, (CAN), ẹ̀ka tipinlẹ Ogun, bẹ Gomina Dapọ Abiọdun lati faaye gba wọn pe kawọn ṣe isin aisun ọdun tuntun ni ṣọọṣi kaakiri ipinlẹ naa lalẹ ọjọ tọdun yii yoo pari ko seso rere rara. Ijọba yari pe oun ko gba, wọn ni asiko Korona la wa, ko saaye ikojọpọ to le ran arun naa lọwọ lati maa pọ si i.
Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Ogun, Alaaji Waheed Oduṣile, lo sọ eyi di mímọ̀ ninu ikede kan ti wọn ṣe nileeṣẹ Radio ipinlẹ Ogun lorukọ ijọba, l’Ọjọruu, Wẹsidee.
Ikede naa fofin de de isin oru mọju ọjọ keji, yala ni ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi káàkiri ipinlẹ ogun, wọn ni ki kaluku ke ‘Api niu yia’ rẹ ninu ile, ki wọn si maa fọkan ba eto naa lọ lori ayelujara.
Ẹ oo ranti pe ninu ọsẹ yii ni ajọ CAN ipinlẹ Ogun bẹ ijọba Gomina Abiọdun pe ko fawọn lasiko diẹ lati ṣesin ọdún tuntun, awọn yoo tẹle gbogbo ofin Korona, awọn ko si ni i pẹẹ ṣetan.
Ṣugbọn ijọba ko gba ipẹ naa wọle, wọn ni afi kawọn oniṣọọṣi ati mọṣalaaṣi gbọrọ sijọba lẹ́nu.