Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu kejila yii, ni wọn sinku Oloogbe AbdulRahman Adewọle Alao Onilu-ọla, iyẹn nile baba naa to wa ni Arinlẹsẹ, l’Abẹokuta.
Awọn eeyan pataki ni wọn peju sibẹ, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ Ayinla Ọmọwura Fans Club International ti wọn ṣayẹyẹ ọjọọbi fun un lọṣu kọkanla, ọdun yii.
Ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Alaaji Rilwan Hassan, to ba ALAROYE sọrọ lori iku agba ọjẹ naa ṣalaye pe bii igba to jẹ pe baba n reti ayẹyẹ nla ti ẹgbẹ naa ṣe fun wọn ki wọn too ku ni, nitori ko ju oṣu kan lọ tawọn ṣe pati nla naa fun un to jade laye yii.
Alaaji Hassan ṣalaye bo ṣe jẹ pe Ọlọrun fun baba yii loju inu to fi mọ pe irawọ wa lara Ayinla, irawọ naa si jade bi wọn ṣe n ba ara wọn bọ. Igba ti wọn ja, ti awọn mejeeji n gbe ara wọn ṣepe, ati igba ti wọn pari ija, gbogbo eyi ni ọkunrin yii sọ pe awọn mọ, titi to fi di pe ipinya de nigba ti Ayinla ku.
Oludasilẹ ẹgbẹ Ayinla Omowura Fans Club International, Ọgbẹni Ṣofẹla Oludayọ, naa fi idunnu ẹ han pe awọn ṣayẹyẹ nla fun baba ki wọn too papoda.
Ọkunrin tawọn eeyan mọ si Adasy naa sọ pe, ‘‘ Ẹkọ ni iku baba yii kọ wa, pe ka maa tọju awọn arugbo wa nigba ti wọn ba wa laye. Ohunkohun ta a ba fẹẹ ṣe fun wọn, ka ṣe e nigba ti wọn wa laye.
‘‘Bi wọn ba pa maaluu mẹwaa nibi isinku yii lonii, ko kan Adewọle mọ, nitori ko si nibẹ. Sugbọn eyi taa ṣe fun wọn loṣu to kọja yii, taa kowo jọ fun wọn lo daa ju. Ode wa ni baba lọ gbẹyin, inu wa dun pe a ṣẹyẹ to yẹ fun wọn loju wọn.’’
Nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ni wọn gbe baba wọ kaa ilẹ lọ. Awọn ọmọ wọn, ọmọọmọ, ara adugbo, Alagba Tunde Kelani, diẹ ninu awọn ọmọ Ayinla Ọmọwura atawọn mi-in ni wọn wa nibi eto isinku naa.