Bi eti Buhari ko ba di, o yẹ ko gbọ ohun ti Kukah n sọ
Bo ba ṣe pe Aarẹ Muhammadu Buhari ṣi n gbọrọ, ti laakaye rẹ si n gbe ọrọ ti awọn eeyan ba sọ, o yẹ ko feti si ọrọ ti Olori ijọ Aguda agbegbe Ṣokoto, Biṣọọbu Kukah, sọ. Ootọ ọrọ kan ko ju bẹẹ lọ, ẹni to ba leti ko gbọ ni. Ẹni-Ọwọ Kukah n ṣe iwaasu ni, o waa ni gbogbo ẹni yoowu to ba jẹ olododo ni Naijiria lo gbọdọ mọ pe to ba jẹ Buhari ki i ṣe Musulumi lati ilẹ Hausa ni, ko le ṣe ida mẹwaa ohun to n ṣe yii ti aburu ko ni i ṣẹlẹ si ijọba rẹ. O ni bi ki i baa ṣe pe awọn ṣọja fibọn gbajọba lọwọ rẹ, Naijiria yoo ti wa ninu ogun abẹle bayii, nitori iwa ẹlẹyamẹya ti Buhari n hu, to sọ ohun gbogbo ni Naijiria di ti awọn Fulani, ati awọn Hausa to ba jẹ Musulumi pata. Kukah ni ohun ti Buhari fi han gbogbo aye ni pe oun fẹran awọn ẹya oun, ati ẹsin oun, ju Naijiria funra rẹ lọ. O ni Buhari ko kọ bi Naijiria fọ pata, tabi bi Naijiria ba jagun, ki ẹya tirẹ ṣaa ti wa loke ni. O ni bo ba jẹ ẹlomi-in lati inu ẹya mi-in lo n ṣe bayii ṣejọba, awọn ṣọja yoo ti gbajọba naa kuro lọwọ rẹ, ṣugbọn pe ki Buhari ati awọn eeyan rẹ mura si i o, Ọlọrun wa loke to n wo ohun ti kaluku n ṣe. Bo ba jẹ Yoruba lo sọ iru ọrọ bayii, wọn yoo ni o koriira Buhari ni, tabi ki wọn sọ pe ko fẹran awọn Hausa. Ṣugbọn Kukah ki i ṣe ọmọ Yoruba, ki i ṣe Ibo, ọkan lara wọn lati ilẹ Hausa ni. Ṣugbọn o sododo ọrọ, nitori bi a ba ti yọwọ awọn olorikori ti wọn n jẹ ninu idarudapọ to wa niluu bayii, ko sẹni kan ti yoo sọ pe ohun ti ijọba Buhari n ṣe yii dara. Ohun gbogbo bajẹ mọ wọn lori pata, wọn ko ri kinni kan ṣe ko yanju. Ariwo ti wọn n pa tẹlẹ ni pe awọn waa ṣejọba ki awọn eeyan ma kowo jẹ mọ, ṣugbọn ikowojẹ to n ṣẹlẹ labẹ tiwọn buru ju eyi ti a ti ri tẹlẹ lọ. Buhari loun yoo tun ọsibitu wa gbogbo ṣe debii pe ko ni i si ẹni ti yoo lọ siluu oyinbo lọọ gba itọju mọ, ṣugbọn Buhari funra ẹ lo n ṣaaju awọn to n lọ. Buhari ni oun yoo sọ owo naira di dọla kan tiwa lati tun eto ọrọ aje wa ṣe, ṣugbọn owo dọla ti n lọ si bii ẹẹdẹgbẹta naira laye ijọba Buhari, ohun ti ko ṣẹlẹ ri nilẹ wa. Kaka ki Buhari tun ọrọ aje tiwa ṣe, orilẹ-ede Nijee lo doju ijọba rẹ kọ, nibẹ ni wọn n ko owo wa lọ lati fi tun tiwọn ṣe nibẹ. Eyi to buru ju ni ti eto aabo, ti Buhari si laju silẹ, ti awọn Fulani sọ Naijiria di ilu ti ko loluwa, ti wọn sọ Naijiria di ilu ti awọn janduku n gbe, nibi ti wo fi ṣe ile, ti wọn si n ṣejọba wọn. Ọrọ naa buru debii pe ko si ẹni to mọ ohun to le pada waa ṣẹlẹ si wa nilẹ yii, bẹẹ awọn Fulani ni wọn wa nidii gbogbo aburu yii! Bi Fulani ba jiiyan gbe, ijọba Buhari yoo ran Fulani mi-in si wọn, wọn yoo si ko owo fun wọn lati fi Fulani naa silẹ. Bi Fulani onimaalu ba paayan, ti wọn jẹ oko oloko, tabi ti wọn ji awọn obinrin olobinrin gbe, koda, bi ọlọpaa mu wọn, ijọba Buhari ko ni i jẹ ki wọn ṣe kinni kan fun wọn. Ohun to fa gbogbo idarudapọ to wa niluu wa bayii ree, ko si kinni kan to dara, tabi ohun kan ti eeyan le tọka si pe ijọba yii ṣe ni ti daadaa. Ṣugbọn awọn eeyan ko le sọrọ, nitori ijẹkujẹ to ti ba wọn laye jẹ. Ṣugbọn iru nnkan bayii ki i lọ pẹ titi, yoo pada di wahala ni, wahala naa yoo buru, nitori awọn ti wọn n ṣebajẹ yii ati awọn ti wọn n ti wọn lẹyin ati awọn ti wọn jọ n purọ funra wọn, gbogbo wọn ni rogbodiyan ti yoo ti idi ọrọ naa jade yoo gbe mi, yoo gbe wọn mi tọmọtọmọ ni paapaa. Nitori ẹ, ti Buhari ba ni eti to fi n gbọran, ẹ ni ko feti si ohun ti Ẹni-Ọwọ Kukah n sọ o.
Ṣugbọn ara yin kọ ootọ ọrọ ṣa
Bi kinni kan ba wa to ba aye ijọba Buhari yii jẹ, ki ara awọn ti wọn n ṣejọba kọ ootọ ọrọ ni. Ara awọn eeyan yii ma kọ ootọ ọrọ o. Bi kinni kan ba ṣẹlẹ, ti awọn ti wọn mọ idi ọrọ, tabi bi nnkan ti jẹ, ba si n ṣalaye, ti wọn n ṣe ikilọ fun ijọba yii, ohun ti ẹ oo ri ni eebu, ati ọrọ buruku ti awọn ti wọn n ṣẹjọba yoo bẹrẹ si i sọ jade lẹnu si gbogbo ẹni to ba gba wọn nimọran. Iru ẹ tun ni ọrọ ti Fada Kukah yii o. Bi Kukah ti fi gbogbo ara ṣalaye, to si sọ ootọ ọrọ fawọn ti wọn n ṣejọba, loju-ẹsẹ ni Lai Muhammed ti jade, to bẹrẹ si laagun niwaju ori, to n ṣa gbogbo irọ jọ, to si n bu ọkunrin naa pe ko yee sọsọkusọ. O ni Kukah n sọrọ to le doju ijọba bolẹ ni, awọn ti awọn n ṣejọba ko si ni i laju awọn silẹ, ki awọn maa wo ẹnikan niran nitori pe o jẹ ẹni-ọwọ, tabi ojiṣẹ Ọlọrun, ko maa waa sọrọ ti Ọlọrun ko ran an lati fi ba ijọba tawọn jẹ. Lọrọ kan Lai Muhammed ni ki Kukah ṣọra ẹ, nitori ohun to n fa lẹsẹ yẹn yoo le fun un to ba ṣẹlẹ. Lara awọn eeyan-keeyan to n ba aye ijọba Buhari jẹ lẹ ri yẹn. Awọn yii ko jẹ ba Buhari sọ ootọ ọrọ, bo tilẹ jẹ pe wọn mọ pe ohun ti baba naa n ṣe ko dara. Nitori ohun ti wọn n jẹ lẹnu, bi wọn ti n purọ fun Buhari ni wọn yoo maa pa fun araalu, ko si si ohun ti wọn ṣe n ṣe bẹẹ ju pe ki wọn le sọ pe wọn n ṣiṣẹ gidi fun Buhari, ki ipo ti wọn wa ma si ṣe bọ lọwọ wọn. Nibo ni Lai Muhammed to n sọ kantankantan yii wa nigba ti Kukah, Abdul-Salami ati awọn agba meji mi-in lọọ jokoo ti Goodluck Jonathan nigba ti Buhari wọle ibo, tawọn kan si n sọ pe ki Jonathan ma gbejọba silẹ, pe bo ba da eto idibo naa ru, ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ, ko fi ṣọja yanju ẹni to ba ta ko o. Ṣebi awọn Kukah yii ni wọn lọọ ba a ko ma sẹ bẹẹ, ti wọn jokoo ti i titi to fi pe Buhari, to si ki i ku oriire, to si gba lati gbejọba silẹ fun un. Bi Kukah ba ya awọn onijẹkujẹ bii iru Lai Muhammed, oun ko jẹ de ọdọ Jonathan sọ iru ọrọ bẹẹ, nitori Jonathan n ṣe daadaa si wọn. Bo ba jẹ iru awọn Lai Muhammed ni lọjọ naa lọhun-un, wọn yoo ni ki Jonathan ma lọ ni, wọn yoo ni awọn ọta rẹ lo wa nidii ibo naa, ko ma gbejọba silẹ fun wọn. Ohun ti Kukah ṣe yii ti fi i si ipo oloootọ ati olododo ju eyi ti awọn Lai n ṣe yii lọ. Orukọ rẹ si dara niluu ju ti Lai ati awọn eeyan rẹ lọ.Bo ba jẹ awọn kan wa ti wọn n ri Buhari, ohun pataki ti wọn gbọdọ sọ fun un ni pe ko maa gbọ ootọ ọrọ, nitori to ba n feti si ootọ ọrọ nikan ni ijọba rẹ le dara. Ṣugbọn to ba jẹ iru awọn Lai Muhammed yii lo n feti si, awọn gan-an ni yoo ti ijọba rẹ yii ṣubu, ki i ṣe PDP tabi ẹlomi-in, awọn ti wọn n purọ fun un yii ni yoo doju ijọba rẹ bolẹ lọjọ kan.
Ẹ jẹ ka bi wọn, awọn wo lo n ba Buhari lorukọ jẹ
Bẹẹ naa ni Garba Shehu, oun naa tun gbe tiẹ jade lọsẹ to kọja pe ki awọn ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ba Buhari lorukọ jẹ lọ lọọ dẹyin ninu iru iwa bẹẹ bi wọn ko ba fẹẹ kan idin ninu iyọ. O ni o ti di aṣa fun awọn kan ki wọn kan maa ba Buhari lorukọ jẹ ṣaa. Ohun to jẹ ki ọkunrin yii maa fi ete oke lu tilẹ lori asan bayii ni pe iwe iroyin nla kan niluu London, Financial Times, gbe awọn ọrọ ododo kan jade nipa Buhari. Ohun ti iwe naa sọ ni bi eto aabo ṣe bajẹ to, eyi to si bi iwe iroyin naa ninu ju lọ ni pe ijọba yii n parọ. O ni awọn ọmọleewe ti wọn ji ko lọjọsi lati ileewe giga ni Katsina, owo gọbọi nijọba yii fi gba wọn pada lọwọ awọn Boko Haram to ji wọn ko, pe iru owo sisan fun awọn janduku bẹẹ ko dara, nitori yoo kan maa tubọ fun awọn afẹmiṣofo naa lagbara si i lati tubọ maa ṣe aburu gbogbo ti wọn n ṣe ni. Iwe iroyin naa ni Buhari ti ba nnkan jẹ jinna, koto ti ijọba rẹ si ti ẹsẹ Naijiria si, fun ọpọlọpọ ọdun, yoo ṣoro fun wọn lati jade. Ohun to bi Garba Shehu ninu ree, lo ba ni awọn ti wọn n ba Buhari lorukọ jẹ ti tun de o, pe wọn ko laju lati ri ohun ribiribi ti Buhari n ṣe. Bẹẹ ni bi wọn ba ti ni ki wọn sọ ohun ti Buhari ṣe yii, irọ ni wọn yoo maa din jọ. Garba ni awọn moju awọn onibajẹ yii, awọn ti wọn ko niṣẹ meji ju orukọ Buhari lati bajẹ lọ. Ṣugbọn o yẹ ki eeyan beere lọwọ awọn amukunmẹkọ wọnyi pe ta lo n ba orukọ Buhari jẹ, ṣe awọn araalu ati awọn ọjọgbọn ti wọn mọ ohun to n lọ ni tabi awọn alaimọkan ti ijẹkujẹ ti wọn n jẹ ninu ijọba yii ti gba laakaye wọn. Awọn ti wọn mọ bi Naijiria ti ri ki Buhari too gbajọba ni wọn sọrọ, wọn si mọ pe ohun to n ṣẹlẹ laye ijọba rẹ ko dara. Kaka ki awọn ti wọn si n ba a ṣiṣẹ gbọ iru ọrọ bẹẹ ki wọn fi ṣe itọnisọna fun ọga wọn, ẹwu ija ni wọn yoo gbe wọ sọrun, ti wọn yoo si maa sọrọ to le dun Buhari ninu, yatọ si ọrọ to le tun nnkan ṣe. Ọlọrun yoo mu wọn. Yoo mu wọn dandan ni o, nitori awọn gan-an lonibajẹ ti wọn n pe ara wọn leeyan rere, awọn ni wọn n ba Buhari lorukọ jẹ, ti wọn si ni nnkan daadaa lawọn n ṣe fun un!
Oku baba Kwakwanso ati Koro
Gbogbo igba ni ikilo n jade, ki i ṣe ni Naijiria nikan, kari aye ni. Lori arun Korona yii ni o, ti wọn n kilọ pe ki awọn eeyan ma pe jọ rẹpẹtẹ soju kan, ki wọn yẹra funra wọn, ki wọn si maa lo ibomu. Awọn kan ko gba pe arun yii wa, bẹẹ arun naa wa nigboro, ẹni ti ko ba ṣora ẹ, yoo fori ko o. Bẹẹ ni ki i ṣe arun olowo nikan, bo ba mu talaka naa, yoo ṣe e bo ti n ṣe awọn to ku ni. Bi awọn ara Isalẹ Odo-Ọya, iyẹn awọn Yoruba ati Ibo, ti n gbiyanju lati pa ofin Korona yii mọ, awọn eeyan wa ni Oke-Ọya, nilẹ Hausa lohun-un, ko nigbagbọ pe kinni kan n bẹ to n jẹ Korona, ati pe gbogbo arun to ba ti de to n paaayan, amuwa Ọlọrun ni. Bẹẹ ko ri bẹẹ, nitori Ọlọrun ko sọ pe ki a ma tọju ara wa, tabi ki a ma yẹra fun ajakalẹ arun, Ọlọrun ko ni ki a fi ara wa silẹ fun iku pa. Bi eniyan ba ri ohun to ṣẹlẹ nibi ti wọn ti n sinku baba Kwakwanso, gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ to tun dupo aarẹ nigba kan, oluwarẹ yoo mọ iyatọ to wa laarin awọn eeyan isalẹ nibi ati awọn ti wọn wa loke lọhun-un, alaigbọran ati alaimọkan pọ ju awọn ọlọgbọn ati onilaakaye lọ. Lọdọ tiwọn yii, ko si kinni kan to jọ wọn loju, ofin ko jẹ kinni kan fun wọn, bẹẹ ni wọn ko si kọ lati fi tiwọn ko ba awọn mi-in. Bi ajakalẹ arun ba tan kiri nitori bi wọn ṣe rọ pọ nibi oku baba Kwankwaso yii, ti ero n lọ bii ẹgbẹẹgbẹrun, ti wọn ko si bo imu tabi bo ẹnu, ohun ti wọn yoo maa sọ ni pe ki ijọba Naijiria ko owo jade lati fi tọju wọn. Owo ti wọn fẹẹ ko jade yii ki i ṣe owo to wa lati ọdọ wọn, ki i ṣe owo ti wọn ṣiṣẹ fun, owo to wa lati ọdọ tiwa nibi ni. Owo yii ni wọn yoo na, bi wọn ko si fun wọn, wọn yoo bẹrẹ ija, bẹẹ awọn ni wọn ko ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ijọba to ba fẹran Naijiria, ijọba to gbọdọ ṣeto ilaniloyẹ, eto ẹkọ to dara fun ilẹ Hausa ni, ki i ṣe ijọba to n fọwọ pa wọn lori, ti yoo maa ko owo ti wọn ba pa nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo fun wọn. Afọwọfa ni wọn n ṣe yii o, bi ajakalẹ arun ba si gbilẹ nibẹ lojiji, ki ẹnikan ma ko owo Naijiria fi tọju wọn, ki wọn na owo ara wọn fi ṣetọju ara wọn.