Lẹyin ọjọ mejila nigbekun, aburo aṣofin ti wọn ji gbe bọ lọwọ awọn ajinigbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Lẹyin to lo ọjọ mejila nigbekun awọn ajinigbe, to si lo ọjọ akọkọ ninu ọdun tuntun, 2021, ninu aginju igbo kijikiji, aburo aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ  Jumọkẹ Babalọla-Oludele, ti bọ lọwọ awọn ajinigbe.

 

Jumọkẹ, aburo Ọnarebu Sunkanmi Babalọla, ni wọn ji gbe nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, ti wọn si pe awọn mọlebi ẹ pe miliọnu lọna ogun (₦20m) lawọn yoo gba lọwọ wọn ki awọn tóo le fi i silẹ.

 

ALAROYE gbọ pe laaarọ Satide, ọjọ Abamẹta lobinrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn naa deede yọ si awọn ẹbi ẹ kulẹ, lẹyin to bọ lọwọ awọn ajinigbe.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ẹgbọn obinrin yii, Ọnarebu Babalọla, sọ pe ni nnkan bíi aago mẹfa idaji Satide laburo oun pada sile ọkọ ẹ.

 

O ni ọfẹ l’Abilekọ Jumọkẹ gba ominira kuro nigbekun awọn ajinigbe, awọn ko fun awọn obayejẹ eeyan naa ni nnkan kan.

Leave a Reply