Ọlawale Ajao, Ibadan
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii, eeyan marun-un lajakalẹ arun Korona ran lọ sọrun apapandodo nipinlẹ Ọyọ.
Ajọ to n ṣe kokaari ọrọ ajakalẹ arun nilẹ yii, NCDC, lo fidi iroyin yii mulẹ lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide.
Ninu akọsilẹ esi ayẹwo arun Korona to jade lalẹ ọjọ naa, ipinlẹ Ọyọ lo wa nipo kin-in-ni ta a ba n sọ nipa iye ẹmi eeyan to bọ sọwọ aṣekupani arun naa ni ipinlẹ kọọkan.
Ipinlẹ Kano lo wa nipo keji, nitori eeyan meji lo j’Ọlọrun nipe latara arun yii lọjọ naa.
Ipo karun-un ni ipinlẹ Ọyọ wa bayii ta a ba mu awọn ipinlẹ ti ajakalẹ arun Korona ti n ṣọṣẹ ju lọ ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jakejado orileede yii.
Apapọ eeyan mọkanlelaaadọta (51) lo ti padanu ẹmi wọn sinu ajakalẹ arun yii nipinlẹ Ọyọ. O si ti fi meji le lẹgbẹrun kan ati ọọdunrun eeyan (1,302) ti Korona ti ran lọ sọrun aremabọ jake-jado orileede yii.