Faith Adebọla
Ogbontarigi ọmọwe ati onkọwe ilẹ wa nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe o nidii toun ko fi sọrọ nipa iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari mọ, o loun diidi ṣepinnu naa ni, tori oun ko fẹ kori oun daru rara, tori o san keeyan gbagbe nipa ijọba yii patapata.
Lori eto ifọrọwanilẹnuwo kan tileeṣẹ tẹlifiṣan kan, Kaftan TV, ṣe fun un lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, lo ti sọrọ ọhun.
Nigba ti wọn bi Ṣoyinka leere pe o tojọ mẹta to ti da si ohun to n lọ nipa iṣakoso Aarẹ Buhari, lọgan lọkunrin naa fesi pe didakẹ toun dakẹ ki i ṣe akọsẹba rara, oun o si ṣetan lati sọrọ kan nipa iṣakoso ọhun lodidi, tori o san keeyan ma da ọpọlọ ẹ laamu lori ẹ rara, o daa keeyan kuku mọkan kuro nipa iṣakoso to wa lode yii.
O ni loootọ, oun le sọrọ nipa awọn nnkan kọọkan to ba ṣẹlẹ tabi to yẹ ko ṣẹlẹ o, ṣugbọn lati sọrọ nipa ijọba Buhari lodidi, oun ti gbagbe ẹ ni toun.
O leeyan to ba nifẹẹ alaafia, ti o fẹẹ ko ara ẹ siyọnu, afi konitọhun ma tiẹ ronu pe ijọba gidi kan wa lorileede yii lọwọ yii.
Ṣoyinka tun sọrọ nipa ọna marosẹ Eko si Ibadan, o ni ẹẹmeji ọtọọtọ loun ti ni ijakulẹ nla lori ipo ti ọna ọhun wa. O ni lọjọ kan, laipẹ yii, odidi wakati mẹfa loun lo lati Abẹokuta si Eko, ọjọ kan si wa to jẹ pe niṣẹ loun wọgi le ibi eto pataki kan to yẹ koun lọ latari bi ọna naa ṣe buru to.
Amọ ṣa o, o ni inu oun dun si reluwee Eko si Ibadan ati ọna oju irin ti wọn n ṣe lọwọ. O ni teeyan ba wo bo ṣe nira to lorileede yii lati ṣaṣeyọri iṣẹ bẹẹ, o yẹ keeyan lu wọn lọgọ ẹnu, ṣugbọn teeyan ba fi wera wọn pẹlu tilu oyinbo, ko jọ ara wọn rara.