Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkan pataki lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, to tun ti figba kan ṣoju awọn eeyan Aarin-Gbungbun Ọṣun nile-igbimọ aṣofin agba, Sẹnatọ Adebayọ Salami ti jade laye.
Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe agba oloṣelu naa ku lorileede Amẹrika, ti ko si ti i si ẹnikẹni to le sọ pato nnkan to pa a.
Odun 1999 ni baba naa di aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oṣelu AD.