Sanwo-Olu ṣabẹwo si Buhari l’Abuja

Faith Adebọla, Eko

 

Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ati Aarẹ Muhammadu Buhari tun foju rinju l’Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, latari ati wa iranwọ ijọba apapọ lati mu ki atunkọ awọn dukia ijọba ti wọn bajẹ nigba iwọde ta ko SARS to kọja, ya kankan.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba to wa l’Alausa, Ikẹja, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee yii, Sanwo-Olu ni oun ṣẹṣẹ de lati ibi ipade toun lọọ ṣe l’Abuja ni, o loun lọọ fi ibi ti iṣẹ de duro lori atunkọ awọn dukia to bajẹ naa han, kijọba apapọ le pese iranwọ to yẹ.

O ni inu Aarẹ Buhari dun si isapa tawọn ti ṣe, awọn iṣẹ ilu ati atunkọ to n lọ lọwọ nipinlẹ Eko.

Gomina ni, “Iṣẹ atunṣe gidi n lọ lọwọ. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe mọ, ile teeyan fi ọjọ kan wo, o le gba ọdun mẹwaa lati tun un kọ. Ṣugbọn a ti n mu iṣẹ atunkọ naa ni ọkọọkan ejeeji, o n lọ wẹrẹwẹrẹ.

‘’Fun apẹẹrẹ, a ti bẹrẹ si i ran awọn olokoowo kee-kee-ke ti wọn padanu okoowo ati dukia wọn lọwọ. Ọpọ ninu wọn ti bẹrẹ ọrọ-aje wọn pada diẹdiẹ. Ko ni i pẹ ta a fi maa de ọdọ awọn olokoowo nla. Bẹẹ la o si dawọ duro lori atunkọ awọn teṣan ọlọpaa atawọn ile ijọba mi-in tawọn janduku fọwọ ba.’’

O lawọn dukia nla mi-in bii eto irinna, ile atawọn nnkan iṣẹmbaye ti wọn bajẹ, o le ṣe diẹ kawọn too bẹrẹ si i tun wọn kọ, tori owo ti atunṣe wọn maa na ijọba ko kere, iṣẹ nla si ni.

Lori ọrọ Korona to n ba ipinlẹ Eko finra lẹẹkeji, Gomina Sanwo-Olu ni ọpọ awọn ti wọn n gba itọju lọwọ nilo afẹfẹ ọsijin (oxygen) si i, tori ọwọ arun naa le gidi lọtẹ yii ju ti igba akọkọ lọ.

O loun sọrọ eyi naa fun  Aarẹ Buhari, eto si maa bẹrẹ lati kọ awọn ibudo afẹfẹ osigin ni kiakia, lati kapa itankalẹ arun ọhun, ki wọn si le doola ẹmi awọn olugbe Eko to fara kaaṣa Korona.

Leave a Reply