Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari ipaniyan to n fi gbogbo igba ṣẹlẹ lawọn ibi kan nipinlẹ Ogun, eyi ti ki i yee ni ọwọ awọn aṣọbode ninu, ọga agba awọn ẹṣọ naa nipinlẹ yii,(Ẹkun Ogun kin-in-ni) Ọgbẹni Peter Kolo, ti beere fun ifọwọsowọpọ awọn ọba alaye nipinlẹ yii, bẹẹ lo ni ikọ awọn ki i ṣe apaayan rara.
Opin ọsẹ to kọja yii ni ọga kọsitọọmu naa ṣabẹwo sawọn ọba mẹta nipinlẹ Ogun. O de ọdọ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, ọdọ Agura, Ọba Saburi Babajide Bakare ati ọdọ Olu ti Kọbapẹ, Ọba Olufẹmi Allen Taylor.
Gẹgẹ bi ọga kọsitọọmu naa ṣe wi, ikọ aṣọbode ilẹ yii ki i ṣe ẹgbẹ mujẹmujẹ, o ni ikọ to n tẹle ofin to de iṣẹ wọn ni. Peter Kolo sọ pe idi niyẹn tawọn fi nilo ifọwọsowọpọ awọn ọba alaye, lati ba awọn eeyan wọn sọrọ, paapaa awọn onifayawọ inu wọn, lati ri i pe kọsitọọmu ki i ṣe ọta wọn, iṣẹ wọn ni wọn n ṣe lati tun ọrọ aje ilẹ wa ṣe.
Lori ipaniyan to ṣẹlẹ l’Ayetoro loṣu to kọja, ọga kọsitọọmu yii loun ti gbe awọn igbesẹ kan kawọn to yẹ ko gbọ le gbọ, o loun nigbagbọ pe iru ẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ.
Ninu ọrọ rẹ, Alake ilẹ Ẹgba, fi atilẹyin rẹ han fun awọn aṣọbode, bakan naa si ni Ọba Agura ati Kabiyesi ilu Kọbapẹ tawọn mejeeji jẹ oṣiṣẹ-fẹyinti nileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa, fi atilẹyin wọn han fawọn kọsitọọmu yii, wọn ni ki nnkan daa lawọn n fẹ, awọn paapaa ko fara mọ ipaniyan.