Ọlawale Ajao, Ibadan
Bi ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji (38) kan, Babafẹmi Gbenga, ba ri wolii kan riran si i pe nipasẹ ere ṣiṣe ni yoo gba rọrun alakeji, ati pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lọjọ naa yoo jẹ, ọkunrin mẹkaniiki yii iba wulẹ ma ti jade rara lọjọ Tusidee to kọja yii debi ti yoo kọju eréepá si ẹni ti yoo gbẹmi ẹ ni rèwerèwe.
Gbenga ati obinrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Efe Gift, ko ṣẹṣẹ maa bara wọn ṣere, ṣugbọn bi ere ti wọn ti jọ maa n ṣe tẹlẹ ti ki i dija yii ṣe di ohun ti ọmọbinrin Ibo yii n gun ọrẹ ẹ pa, lo sọ Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu kin-in-n,i ọdun 2021 yii, di ọjọ buruku eṣu gbomi mu fun wọn.
Bi ki i baa ṣe pe iṣẹlẹ yii ti wa ninu akọsilẹ Ẹlẹdaa, ṣebi aanu lọkunrin yii fẹẹ ṣe to fi lọọ pade iku ojiji, ẹnikan lo fẹẹ ran lọwọ to fi lọ sibi ti wọn ti pa a.
Iwadii akọroyin wa fidi ẹ mulẹ pe ọti ẹlẹridodo lo n mu lọwọ jẹẹjẹ ni ṣọọbu ọga ẹ to n kọ ọ niṣẹ mẹkaniiki nitosi ileeṣẹ awọn aṣọbode (kọ́sítọ́ọ̀mù) laduugbo Ikọlaba, n’Ibadan, ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ naa. Ẹnikan to sọ pe ori n fọ oun ni Gbenga pinnu lati lọọ ba ra oogun nigba ti onitọhun ko ri ọmọde kankan to maa ran loogun yẹn nitosi.
Oogun ̣ọhun lo lọọ ra nitosi ṣọọbu wọn nibẹ to fi fẹsẹ kan ya sọdọ Gift, ṣe ẹgbẹ kan ibi ti wọn ti n ta oogun lobinrin naa ti maa n hun apẹrẹ, to si maa n patẹ awọn ọja naa sẹgbẹẹ titi ládojúkọ ileeṣẹ awọn aṣọbode.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe ṣalaye fakọroyin wa, “Nibi ti obinrin alapẹrẹ yẹn ti bẹrẹ mọlẹ to n ṣiṣẹ lọwọ ni Gbenga ti fọwọ mejeeji rìn ín lẹgbẹẹ látẹ̀yìn. Bẹẹ niyẹn yán ọwọ sẹyin lojiji, ti ọbẹ to mu lọwọ si ya Gbenga lọwọ.
“Ọrọ yii di ibinu Gbenga, awọn eeyan bẹrẹ si i bẹ ẹ pe ko fi obinrin yẹn silẹ, ṣugbọn o loun ko ni i gba, nitori pe o ti mu ẹjẹ lara oun. Nibi to ti fẹẹ sun mọ ọn niyẹn ti doju ọbẹ kọ ọ, to si fi gbogbo agbara gun un lọbẹ nigbaaya lẹẹmẹta.
“Lẹyin eyi lo rẹ Gbenga wẹ̀sì, nitori ẹjẹ to jade loju ọgbẹ igbaaya rẹ ti pọ ju. Idi ni pe ọbẹ yẹn ti gún un lọ́kàn, gbogbo bo ṣe n mí lẹjẹ n tú kọ̀líkọ̀lí gba ibi ọkan rẹ jade. Bo ṣe ṣubu lulẹ to bẹrẹ si i japoro iku niyẹn.
“Awọn eeyan ni wọn gbe e dide nibi to ṣubu si. Wọn sare gbe e lọ si UCH (ileewosan ijọba apapọ n’Ibadan). Nibẹ lawọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe o ti ku, wọn lo ti ku ki wọn too gbe e de.”
Nṣe ni ibi ti ọkunrin mẹkaniiki yii ṣubu si ko too di pe wọn gbe e lọ sileewosan kun fun ẹjẹ, afi bii oju ibi ti wọn dunbu ẹran ọdun si. Ipasẹ ẹjẹ ọhun si han loju titi lọ titi de ibi ti wọn ti gbe e sinu mọto lọ sọsibitu.
Araadugbo ọhun kan to pera ẹ ni SP ṣalaye f’ALAROYE pe “Gbenga ati obinrin alapẹrẹ yẹn ko ṣẹṣẹ jọ maa ṣere. Ara ṣọọbu awọn Gbenga kan lo n fẹ obinrin yẹn. Mo ro pe nitori ki ẹni to n fẹ yẹn ma baa ka wọn mọ ibi ti wọn ti n ṣere lo ṣe dà á si ibinu mọ Gbenga lọwọ.”
Ọpọ ninu awọn to b’akọroyin wa sọrọ fidi ẹ mulẹ pe opó ni Gift, oun naa lo pa ọkọ ẹ, bo ṣe fọbẹ gun Gbenga pa naa lo gun ọkọ to bimọ fun lọbẹ pa.
Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe Gbenga ko ti i niyawo, bẹẹ ni ko ti i niṣẹ lọwọ. Lasiko ti baba ẹ ba a riṣẹ si sẹkiteriati ijọba apapọ to wa ni Ikọlaba niṣẹlẹ to da ẹmi ẹ legbodo yii waye.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn ọlọpaa teṣan Ikọlaba ti mu Gift lọ si ẹka to n tọpinpin iṣẹlẹ ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fun iwadii.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan UCH lòkú Gbenga wa nigba ti iwadii awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju.