Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, ti ni ki wọn ṣi lọọ fi ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan, Peter Moses, pamọ sọgba ẹwọn na, lori ẹsun pe o fun ọmọ bibi inu ara rẹ, Peter Patience, loyun.
Iṣẹlẹ yii waye niluu Asẹwele-Korede, nijọba ibilẹ Odigbo, nibi ti olujẹjọ naa ti fipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun lo pọ titi to fi doyun laarin osu kọkanla, ọdun to kọja, si osu kin-in-ni, ọdun tuntun ta a wa yii.
Agbefọba, Ripẹtọ Jimoh Amuda, ni afurasi ọhun ti ṣẹ si abala kejilelọgbọn ninu iwe ofin orilẹ-ede yii ti ọdun 2003, eyi to lodi si lilo ọmọde nilokulo.
Agbefọba ọhun rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju diẹ kawọn ọlọpaa fi pari iwadii ti wọn n ṣe lọwọ.
Ni kete ti wọn ti ka ẹsun kan soso ti wọn fi kan olujẹjọ naa tan lo ti gba pe oun jẹbi, to si n bẹbẹ pe ki adajọ siju aanu wo oun nitori pe aṣiṣe ko kan ọgbọn.
Onidaajọ F. O. Ọmọfọlarin ni ki wọn ṣi lọọ fi ọkunrin naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.