Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọtunba ti ilu Iwo, Oloye Sikiru Atanda, ti sọ pe lati dena wahala to le ṣẹ yọ ti Oluwoo ba tẹsiwaju ninu ipinnu to ṣe pe oun fẹẹ fi akọwe ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun jẹ Ọtun ilu Iwo, loun ṣe tete lọ sile-ẹjọ.
Aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ni ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Iwo, paṣẹ pe ki Oluwoo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, kora ro lori bo ṣe fẹẹ fi Ọnarebu Rasaq Ṣalinsile jẹ Ọtun ilu Iwo lopin ọsẹ yii.
Ninu iwe ipẹjọ ti Ọtunba Atanda pe Ọba Adewale ati Ọnarebu Ṣalinsile, to ni nọmba HIW/3/2021, ni Onidaajọ J. O. Ogunlẹye ti sọ pe igbesẹ ti Ọba Akanbi fẹẹ gbe naa ko le duro rara.
Nigba ti Ọtunba Atanda n ba ALAROYE sọrọ, o ni ijọloju ni igbesẹ Ọba Adewale jẹ fun oun nitori jẹẹjẹ loun jokoo ti Oluwoo ranṣẹ si oun pe oun (Oluwoo) fẹẹ fi oye ọtunba ilu Iwo da oun lọla.
O ni “Ninu oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, ni Ọba Adewale ranṣẹ si mi, o ni oun woye pe mo ni orukọ rere laarin ilu, o si wu oun lati fi mi jẹ Ọtunba ilu Iwo.
“Nitori pe Ọba Adewale jẹ ọba ti mo fẹran, mo gba si wọn lẹnu. Ọjọ keji naa ni wọn fun mi ni satifikeeti gẹgẹ bii Ọtunba ilu Iwo ninu aafin. A fẹẹ mu ọjọ fun iwuye ni wahala Endsars bẹrẹ.
“Ninu oṣu kejila ti gbogbo nnkan rọlẹ la wuye ninu aafin Oluwoo, aye gbọ, ọrun mọ. Mo nawo, mo nara, gbogbo ẹtọ ni mo si ṣe. Afi bi mo ṣe gbọ laipẹ yii pe Ọba Akanbi fẹẹ fi Ọnarebu Ṣalinsile jẹ Ọtun Oluwoo.
“Mo kọkọ jokoo pe ki ni iyatọ laarin Ọtunba ati Ọtun ọba, n ko ri iyatọ kankan. N ko gbọ ọ ri pe ẹni kan jẹ Ọtunba ninu ilu, ẹlomi-in tun jẹ Ọtun ọba. Ko sija kankan laaarin emi ati Oluwoo, bẹẹ ni n ko tanna wa oye, oun lo pe mi to sọ pe oun fẹẹ fi oye Ọtunba da mi lọla.
“Mo mọ pe ti wọn ba jẹ oye yẹn lopin ọsẹ yii, awọn alatilẹyin mi le fa wahala, n ko si fẹ nnkan to le da ilu ru, mo si fẹran kabiesi, mi o fẹ iṣubu rẹ, idi niyẹn ti mo fi tọ ilana ofin, kootu si ti da wọn duro bayii’
Nigba to n sọrọ lori idajọ kootu, Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, sọ pe ọba ni agbara lati fi ẹnikẹni jẹ oye ninu ilu, ṣugbọn gẹgẹ bii ọba to bọwọ fun ofin ile-ẹjọ, Oluwoo yoo dawọ duro lori ifinijoye naa.