Amọtẹkun yinbọn paayan n’Ibadan, lawọn ọdọ ba fẹhonu han

Ọlawale Ajao, Ibadan

Idarudapọ gba agbegbe Mọkọla, n’Ibadan, kan laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ibẹrubojo si ba tọmọde tagba nigba ti ọkẹ àìmọye awọn ọdọ ya bo oju titi lagbegbe naa fun ifẹhonuhan, wọn ni dandan ni ki ijọba wa nnkan ṣe sọrọ awọn Amọtẹkun, ìkọ eleto aabo ilẹ Yoruba ẹka ti ipinlẹ Ọyọ.

Èyí kò ṣẹyin bi awọn oṣiṣẹ ikọ náà ṣe yinbọn pa ọdọmọkùnrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Tosin Thomas.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti ọmọdekunrin olugbe agbegbe Ode Ọlọ́, nigboro Ibadan yii, n ti ibi iṣẹ bọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn oṣiṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun yinbọn lu u.

Olugbe adugbo Mọkọla kan fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa pe, “Nileepo Total to wa laduugbo Mọkọla ni wọn ti yinbọn pa a.

“Mi o mọ ohun tó ṣẹlẹ ti wọn fi yinbọn mọ ọn. Loju ẹsẹ ni wọn ti sare gbe e lọ si UCH (ileewosan ijoba apapọ n’Ibadan) ṣugbọn nígbà tá a máa gbọ àbọ rẹ, wọn lọmọkunrin yẹn ti ku.

“Nigba ti Iya Tosin gbọ pe wọn yinbọn pa ọmọ oun, o sáré lọọ ba awọn Amọtẹkun ni UCH, nibi tí wọn ti lọọ tọju ẹ, o fa aṣọ ya mọ ọkan ninu wọn lọrùn, o ni oun fẹẹ mọ ọran ti ọmọ oun da ti wọn fi pa a. Níbẹ l’Amọtẹkun yẹn ti sọ pe òun máa pa iya yẹn náà pelu ọmọ rẹ to tẹle e lẹyin.”

Ikanra iku ọmọkùnrin ẹni ọdún mọkanlelogun yìí lo mu ki awọn ọrẹ ẹ atawọn ọdọmọkunrin ẹgbẹ ẹ fẹhonu hàn laaarọ yii lagbegbe ibi ti wọn pa oloogbe naa sí ní Mọkọla, n’Ibadan.

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, náà fidi iṣẹlẹ yii múlẹ, o ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun tó ṣokunfa iku ọmọkùnrin náà.

Akitiyan akoroyin wa lati ba agbẹnusọ fún ìkọ Amọtẹkun sọrọ ko seso rere nitori bi obinrin naa ṣe sọ pe òun máa pe akoroyin wa pada, ṣugbọn ti ko mu ileri ọhun ṣẹ titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.

Leave a Reply