Faith Adebọla, Eko
Latari bi esi ayẹwo ti wọn ṣe fawọn kan lara awọn akẹkọọ Fasiti ipinlẹ Eko, (Lagos State University), ṣe fidi ẹ mulẹ pe mẹta lara wọn ti lugbadi arunKorona, awọn alaṣẹ ti tilẹkun gbogbo ile tawọn akẹkọọ n gbe ninu ọgba fasiti naa.
Atẹjade kan ti Ọgbẹni Ademọla Adekọya to jẹ oluṣekokaari ẹka iroyin ati alukoro, CIPPR, fun fasiti ọhun fi sode nipa iṣẹlẹ ọhun laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee yii, sọ pe awọn ti ko awọn akẹkọọ mẹtẹẹta to ni Korona naa lọ si ibudo iyasọtọ, wọn si ti n gba itọju lẹsẹkẹsẹ.
Atẹjade ọhun ka siwaju si i pe: ‘A fẹẹ sọ fun yin pe awọn akẹkọọ yooku ti wọn jọ n lo yara ti lọ fun ayẹwo, a ṣi n duro de esi ayẹwo wọn.
Ni bayii, a ti tilẹkun awọn yara tawọn akẹkọọ n gbe (hostels) to wa lẹka imọ iṣegun (College of Medicine). A rọ gbogbo ẹyin akẹkọọ lati kọri sile yin, ki ẹ si ya ara yin sọtọ fọjọ mẹrinla tẹ ẹ ba dele, titi taa fi maa pari ayẹwo fun yin lati mọ ipo ti ilera yin wa, ati ka le fin kẹmika apakokoro sawọn ile gbigbe wọnyi. A ti gba nọmba tẹlifoonu ati adirẹsi gbogbo awọn tọrọ kan, ka le kan si wọn bo ṣe yẹ.
“Ki akẹkọọ eyikeyii to ba ṣakiyesi ami arun Korona lara rẹ tete pe wa lori aago tabi ki akẹkọọ naa yaa kọri sileewosan ijọba ti wọn ti n tọju awọn oni-Koro kiakia.”
Atẹjade naa pari pe kawọn obi lọọ fọkan balẹ, ijọba Eko maa ṣe gbogbo ohun to ba yẹ lati dena itankalẹ arun aṣekupani yii, wọn ni kawọn obi ma ṣe ko ọkan soke, ṣugbọn ki wọn ri i daju pe awọn pa eewọ Korona mọ, ki wọn si tẹle alakalẹ ijọba lori ẹ.
Wọn tun rọ awọn obi naa lati yẹra fun ifarakinra pẹlu awọn ọmọ wọn to jẹ akẹkọọ LASU, laarin ọsẹ meji tiru ọmọ bẹẹ yoo fi wa ni iyasọtọ labẹle.