Gomina gboriyin fawọn obinrin to dawo kọ ileewe ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ṣabẹwo si ileewe meji ọtọọtọ; Nomadic LGEA Nursery and Primary School, Agindigbi, ati St. Luke LGEA Primary School, Onila, nitosi Agbamu, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, tawọn obinrin ilu dawo jọ lati kọ. O gboriyin fun wọn fun igbesẹ akin ti wọn gbe naa, o si da gbogbo owo ti wọn na lati kọ awọn ileewe ọhun pada loju ẹsẹ.

Ṣe bii ọjọ meji sẹyin ni ileeṣẹ iroyin ilẹ Geẹsi, BBC Yoruba, gbe fidio kan jade, ninu eyi tawọn obinrin bii mẹẹẹdọgbọn ti ṣalaye bawọn ṣe n yọ diẹdiẹ lati inu owo tijọba apapọ n fun wọn, eyi ta a mọ si CCT, lati ọdun 2017, lati le kọ ileewe fun ilu mejeeji naa.

Akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye ni eyi wu gomina lori, idi niyẹn to fi lọọ ṣabẹwo si wọn. O ni gomina beere iye ti wọn ti na lori kikọ awọn ileewe naa, loju ẹsẹ lo fun awọn obinrin ilu mejeeji ni miliọnu kan naira lati fi ṣe owo ti wọn ti na.

Abdulrahman ni, “Ohun to gbe wa wa sawọn ilu yii ni lati ri i pe a pari kikọ awọn ileewe yii. A tun maa fẹ ẹ loju daadaa lati pese awọn kilaasi to maa gba awọn akẹkọọ nirọrun.

“Inu mi dun fun igbesẹ tawọn obinrin yii gbe. O fi han pe loootọ Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣiṣẹ. Ọpọlọpọ eeyan lo ti gbagbe ibi ta a ti bọ, bi gbogbo nnkan ṣe ri ka too gbajọba atawọn ipenija ta a ba nilẹ.

“Aarẹ Buhari gbe eto iranwọ kalẹ ta a mọ si Social Investment Programme, eyi gan-an lo ṣan de ilu mejeeji yii, Agindigbi ati Onila. Dipo ki wọn tọju owo ti wọn gba lọwọ ijọba apapọ fun ara wọn nikan, awọn obinrin yii lo o fun anfaani gbogbo ilu wọn.”

Ajakaye ni gomina tun ṣeleri lati pese awọn ohun amayedẹrun bii omi-ẹrọ, ina mọnamọna atawọn nnkan mi-in fun ilu mejeeji.

Olori ilu Agindigbi Agbamu, Alhaji Ọkanlawọn Adam, gboriyin fun Gomina Abdulrahman fun akitiyan ijọba rẹ lori idagbasoke eto ẹkọ, ati lati ri i pe gbogbo ọmọ lo janfaani ẹkọ to ye kooro. O ni igba akọkọ ree tijọba yoo ṣabẹwo siluu naa latigba ti wọn ti wa nibẹ.

Ọkan lara awọn obinrin to n gbowo lọwọ ijọba apapọ loṣooṣu, Motunrayọ Sulaiman, ni ẹgbẹrun meji aabọ naira ni ẹnikọọkan wọn n da loṣooṣu lati kọ awọn yara-ikawee naa.

Bakan naa, olukọ kan ṣoṣo to wa nileewe alakọọbẹrẹ St Luke LGEA Primary School, Onila,  Mathew Ibiyẹye, rọ ijọba lati pari ileewe naa kiakia, nitori pe awọn obinrin ilu ti gbiyanju niwọnba ohun tagbara wọn mọ.

Adari ọdọ, Abọlaji Sunday, gboriyin fun Gomina Abdulrahman bo ṣe bẹ wọn wo, ati ifẹ to fi han lati mu idagbasoke ba ilu naa.

Leave a Reply