Faith Adebọla, Eko
Idunnu ṣubu layọ fawọn dokita mẹrindinlaaadọrin to kopa ninu iṣẹ abẹ pataki kan to waye lọsibitu Fasiti Ilọrin l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, latari bi Ọlọrun ṣe fun wọn ṣe, ti wọn la awọn ibeji kan to lẹ pọ nikun sọtọọtọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, inu ipaya ati ironu lawọn obi Taye-Kẹhinde naa wa latigba ti wọn ti bi awọn ọmọ naa loṣu kan aabọ sẹyin, tori, yatọ si pe iṣẹ abẹ ni wọn fi bi wọn, awọn ibeji naa ko wa lọtọọtọ bo ṣe yẹ ko ri, niṣe ni awọ ikun wọn lẹ pọ bii ẹni pe ikun kan ṣoṣo lawọn mejeeji ni, bo tilẹ jẹ pe ẹya ara yooku wa bo ṣe yẹ ko wa.
Lọpọ igba ti iru awọn akanda ibeji bayii ba waye, iṣẹ abẹ ni wọn fi maa n ya wọn sọtọ, ṣugbọn ewu nla ni, tori ọpọ igba lo maa n jẹ pe ọkan ninu awọn ẹjẹ ọrun naa ni yoo ye e, igba mi-in si ree, awọn mejeeji le lọ si i.
Ọjọgbọn Lukman Abdul-Rahman, dokita to ṣaaju awọn agba oniṣẹ abẹ atawọn nọọsi to kopa ninu aṣeyọri nla yii, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), pe inu awọn dun gan-an, awọn si ki awọn obi ibeji wọnyi kuu oriire. O ni Ọlọrun lo fun awọn ṣe.