Florence Babaṣọla
Oluwoo ti ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Adewale Akanbi, ti fi ọwọ mejeeji sọya pe ko si ẹnikẹni to ba ni arun Koronafairọọsi to le wọnu ilu naa ti ko ni i ri iwosan.
Lasiko ayẹyẹ ọdun karun-un ti Ọba Akanbi de ori aleefa, eleyii to waye laafin rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, lo ti sọ pe gẹgẹ bii aṣoju Ọlọrun lori aye, gbogbo ọba lo laṣẹ lati beere ohunkohun ti wọn ba fẹ ko ṣẹlẹ si awọn ọmọ ilu wọn lọdọ Ọlọrun.
O ni latigba toun ti de ori aleefa loun ti maa n ba Ọlọrun sọrọ, to si maa n gbọ, iyẹn lo si fa a ti ko fi si akọsilẹ iṣẹlẹ Koronafairọọsi kankan niluu Iwo latigba ti wahala naa ti bẹrẹ.
Ọba Akanbi ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun atilẹyin Rẹ ti oun ri gba lori ilu Iwo. O ni idagbasoke ti ko lonka lo ti de ba ilu naa latigba toun ti debẹ, o si jẹ eyi ti ko ṣẹlẹ ri ninu itan ilu naa.
O ni oun ti ba Ọlọrun sọ ọ pe arun Korona ko gbọdọ kọ lu ẹnikẹni ninu ilu naa, o si da oun loju pe bi ẹnikẹni to ba lugbadi arun naa ba denu ilu Iwo, lọgan ni ara rẹ yoo ya.
Oluwoo waa rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati tẹle gbogbo ilana ati aṣẹ ajọ National Center for Disease Control (NCDC), lori idena itankalẹ arun naa, o si gbadura pe ki Ọlọrun bomi pa ina arun naa lorileede Naijiria ati lagbaaye.