Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ko din lawọn ole agbepo mẹrinlelogun tọwọ awọn ọmọ ogun oju-omi ipinlẹ Ondo, niluu Ilajẹ, tẹ lọsẹ to kọja yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọgagun Shuaibu Muhammed Ahmed to n dari awọn ọmọ ogun oju-omi tilu Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, pe wọn mu awọn afurasi ọhun loju agbami nla to wa laarin ipinlẹ Ondo si Eko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.
Awọn ọkọ oju omi mẹfa to kun fun epo diisu ni wọn ri gba pada lọwọ awọn tọwọ tẹ ọhun gẹgẹ bo ṣe sọ.
Ahmed ni gbogbo igba lawọn n ṣọ awọn agbegbe oju omi to wa ni Ilajẹ ati Ese-Odo, latari idigunjale, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in to wọpọ lawọn ijọba ibilẹ mejeeji.
O ni inu oun dun pupọ pẹlu bi igbiyanju awọn ṣe seso rere lọsẹ to kọja nigba tọwọ tẹ awọn ọdaran naa atawọn ẹru ofin ti wọn ji ko.
Ọga awọn ologun ọhun bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn araalu nipa tete maa fi awọn iṣẹlẹ iwa ọdaran to ba n waye lagbegbe naa to awọn leti.