Florence Babaṣọla
Ọwọ awọn eeyan agbegbe ọja Olufi, niluu Gbọngan, nipinlẹ Ọṣun, ti tẹ tọkọ-tiyawo kan, Isiaka Yinusa ati Ọla, lori ẹsun ole jija.
Aago mẹfa idaji Aje, Mọnde, lawọn mejeeji jalẹkun ṣọọbu kan ninu ọja naa, ti wọn si ji ọpọlọpọ ohun tẹnu n jẹ bii irẹsi, ẹwa, ororo, gaari, koko gbigbẹ (cocoa beans) ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ṣọọbu obinrin naa.
Iwadii ALAROYE fihan pe ọmọ bibi ilu Gbọngan lawọn tọkọ-tiyawo naa, agbegbe Ayepe naa ni wọn si n gbe.
Nigba ti ọwọ tẹ awọn mejeeji, a gbọ pe wọn fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ lagọọ wọn to wa ninu ilu naa.