Ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹjọ wọ gau n’Ifọ, lẹyin iku ọkan ninu wọn ti wọn yinbọn pa

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Ọmọ to ni iya oun ko ni i sun, oun naa ko ni i foju ba oorun lọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kaakiri ipinlẹ Ogun ati awọn ọlọpaa. Mẹjọ ninu awọn ẹlẹgbẹ dudu naa lawọn ọlọpaa tun mu lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹyin wahala ti wọn fa, ti ọkan ninu wọn ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọfada, fi ku iku ibọn.

Bo tilẹ jẹ pe ibudo ọtọọtọ lọwọ ti ba awọn gende ẹlẹgbẹ okunkun Aye ati Ẹyẹ yii, sibẹ, wọn jẹwọ pe ija agba lawọn n ja, to fi di pe Ọfada ba wahala naa lọ.

Awọn tọwọ ba lọjọ Aiku naa ree gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ yii, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe darukọ wọn: Sọji Ọlamilekan; ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Shobande Ọlalekan; ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ati Solomon Fadebi; ẹni ọdun mẹtalelọgbọn. Iyana Coker ni wọn ti mu awọn mẹta yii.

 

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa pẹlu awọn ohun ti wọn ba lọwọ wọn

 

Awọn mẹta yii ni wọn sọ fawọn ọlọpaa pe awọn yooku tawọn jọ n ṣe ẹgbẹ okunkun ti wa lagbegbe Osuke, Onipaanu, l’Ọta, nibi ti wọn ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe tun ja ija mi-in ti wahala yoo tun ba awọn araadugbo.

Kia lawọn ọlọpaa mu ọna Osuke pọn, nibẹ lọwọ ti ba Balogun Oluwaṣeun; ẹni ọdun mejilelogun, Joseph Onwe; ẹni ọdun mẹrinlelogun, Peter Rapheal; ẹni ọdun mejilelogun, ati Yusuf Emmanuel; ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.

Awọn wọnyi tilẹ n ṣepade lọwọ ninu igbo ni kọwọ too ba wọn, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ f’ALAROYE.

Tọheeb Ọlọrunkẹmi lawọn ọlọpaa mu ṣikẹjọ, nibi to ti n gba itọju lọwọ nitori ọta ibọn to ba a lawọn agbofinro ti mu un labule Arobiye, l’Ọta, ẹni ọdun mejilelogun ni.

Eyi lawọn nnkan tawọn ọlọpaa sọ pe awọn ri gba lọwọ awọn gende naa: Ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn ti wọn ko ti i yin mẹfa, foonu oriṣii mẹrin, fila dudu kan ati baagi kekere kan.

Wọn ti gbe oku Ọfada tibọn pa lọ si mọṣuari, wọn si ti ko awọn tọwọ ba laaye yii naa lọ sẹka ọtẹlemuyẹ fun

Leave a Reply