Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ogunjọ, oṣu kejila, ọdun 2020, ni ẹnikan fi ọkada ṣe Saheed Bakare loore pe ko maa fi gbero lagbegbe Atan Ọta, nipinlẹ Ogun, ṣugbọn niṣe lo gbe ọkada naa sa lọ lai ro tẹni to gbe e fun un.
Ohun to ṣe yii lo jẹ ki ẹni to ni ọkada naa fi ọrọ lọ awọn Fijilante So-Safe, pe ki wọn ba oun wa Saheed, ki wọn si gba alupupu oun lọwọ rẹ.
Awọn So-Safe bẹrẹ si i wa Saheed Bakare, ṣugbọn wọn ko ri i titi di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni yii.
Agbegbe Atan Ọta naa ni wọn ti ri i mu, ṣugbọn ki i ṣe pẹlu ọkada akọkọ to gbe sa lọ naa.
Alukoro So-Safe, ACC Mọruf Yusuf, sọ pe ọkada Bajaj mi-in ti nọmba ẹ jẹ SGM 376 VN lawọn ri i ti Saheed n gun, o ni bawọn ṣe mu un niyẹn.
Saheed Bákàrè funra ẹ jẹwọ fawọn fijilante pe oun ji ọkada yii ni.
O ni Ojule kejilelọgbọn, Opopona Kajọla, l’Owode Yewa,