Florence Babaṣọla
Oju ọjọ ko dara lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, fun awọn afurasi onijibiti ori ẹrọ-ayelujara tawọn eeyan mọ si Yahoo bọis pẹlu bawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ṣe ya bo wọn, ti ọwọ si tẹ mọkanla lara wọn.
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ajọ naa, Wilson Uwujaren, ṣe sọ, awọn araalu ni wọn ta ajọ EFCC lolobo nipa irin-ẹsẹ ati iṣẹ ọwọ awọn ọmọ naa, eleyii ti wọn ni o mu ifura lọwọ.
Bayii lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ya bo wọn bii igba ti ita so mọ ẹyin. Ninu iwadii lawọn kan lara wọn ti ni akẹkọọ lawọn, nigba ti awọn kan pe ara wọn ni agbẹ, ti awọn yooku si sọ pe oniṣowo lawọn.
Mọto ayọkẹlẹ olowo-nla mejila ni wọn gba lọwọ wọn, lara rẹ ni Toyota Highlander SUV, Mercedez Benz, GLK 350 SUV, Acura SUV, Honda Crosstour, Toyota Venza ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni wọn gba ọpọlọpọ foonu, kọmputa agbeletan atawọn nnkan mi-in lọwọ wọn.
Wilson sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ẹni ti ko ba lọwọ ninu ẹsun naa laarin wọn, ki alaiṣẹ ma baa ku sipo ẹlẹṣẹ, ati pe ni kete tiwadii ba ti pari lawọn ti ajere iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori yoo foju bale-ẹjọ.