Faith Adebọla
Gbajumọ ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, tabi Igboho Ooṣá ti mu ileri rẹ ṣẹ, pẹlu boun atawọn ọmọlẹyin rẹ ṣe ya wọ ilu Igangan, lagbegbe Ibarapa, nijọba ibilẹ Ariwa North, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, yii, ale-sa-wọgbo ni wọn le awọn Fulani inu ilu naa, awọn ọdọ si dana sun awọn ile Seriki Fulani wọn.
Gẹgẹ bii Ọgbẹni Akeem Lawal tọrọ naa ṣoju ẹ ṣe ṣalaye fakọroyin wa, niṣe lawọn ọdọ ilu yii atawọn ọdọ mi-in lati awọn ilu ti ko jinna bii Ayetẹ ati Tapa sare darapọ nigba ti Sunday debẹ, wọn n pariwo pe ‘olugbala awọn mẹkunnu lo de yii, ọjọ ẹsan ti de’.
Wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ ti Sunday wa ninu rẹ lo ṣaaju awọn bọọsi to ko awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn lo ju ọgọrun meji lọ, bẹẹ ni mọto awọn ọlọpaa ati DPO teṣan ọlọpaa to wa l’Ayetẹ tẹle wọn.
Bi Igboho Ooṣa ṣe bọ silẹ, taara lo mori le ile ẹni to jẹ olori awọn Fulani lagbegbe naa, ti wọn n pe ni Seriki wọn, to si sọ fun un pe ko bẹrẹ si i palẹ ẹru rẹ mọ kiakia. O loun ko ba tija wa, oun kan waa sọ fun un ni pe gbedeke ọsẹ kan toun fun oun (Seriki naa) atawọn Fulani yooku lati fi agbegbe naa silẹ ki i ṣe ọrọ ṣereṣere rara, bi wọn ba re kọja akoko naa, ki wọn fara mọ ohunkohun to ba tidi ẹ yọ ni.
Lori kankere giga kan ti Sunday ti n ba wọn obitibiti ero naa sọrọ, o ni ki i ṣe agbegbe Igangan tabi ti Oke-Ogun nikan lawọn ko ti fẹẹ ri awọn Fulani mọ o, gbogbo ipinlẹ Ọyọ ni.
O ni ọmọ Oke-Ogun loun, oun ko si le wa lagbegbe naa kawọn ajoji maa pa awọn ọmọọya oun bii ẹni pa adiyẹ, tori ẹ loun ṣe ti kilọ ṣaaju kọrọ too de ibi to de yii.
Wọn ni Seriki Fulani naa sọrọ pe ki i ṣe awọn Fulani nikan lo n paayan lagbegbe naa, pe awọn Yoruba naa wa lara awọn amookunṣika ọhun, ni Sunday ba beere pe ko tọka tabi darukọ awọn Yoruba to ba mọ, ṣugbọn olori awọn Fulani naa ko le darukọ kan.
Wọn ni bi Sunday ṣe n pari ọrọ rẹ lawọn ọdọ kan ti wọn ti mura ija lọọ gba ẹyin fina si awọn ile koriko to wa ni aba (Gaa) Seriki yii, ti ile ati awọn dukia to wa nibẹ si jona deeru loju ẹsẹ.
Bakan naa lawọn ọdọ yii tun dana saarin titi, ti wọn si n kọrin pe awọn o fẹẹ fi Fulani kan nilẹ yii mọ.
Ṣaaju ni Sunday Igboho ti kede pe ọjọ meje pere loun fun awọn Fulani lati palẹ ẹru wọn mọ, ki wọn si fi agbegbe naa silẹ, latari bi akọlu ati ipaayan nipakupa ṣe n waye lemọlemọ lagbegbe ọhun.
Sunday ni oun ko ni i gba kawọn tawọn dibo fun, tawọn mọ bi wọn ṣe dori aleefa, waa ko Fulani apaayan ka awọn mọ, o si loun ko bẹru boya ọlọpaa kan maa mu oun, ẹni lo ba fẹẹ mu oun, oun ṣetan lati ri onitọhun.