Jide Alabi
Eeyan mẹrin lo ku nifọna-fọnṣu nibi ijamba mọto kan to ṣẹlẹ niluu Ọttẹ, loju ọna Ogbomọṣọ si Ilọrin, eyi ti ko jinna si papakọ ofurufu Ilọrin, ni ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo FRSC, nipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ere asapajude ti bọọsi akero elero mejidinlogun naa n sa lo ṣokunfa ijamba ọhun.
Awọn tọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe tirela to n lọ jẹẹjẹ rẹ ni mọto naa fẹẹ ya silẹ ki nnkan too yiwọ lojiji. Lasiko naa lo lọọ sọ lu tirela naa latẹyin, ti bọọsi ọhun si gbokiti lera lera, lẹyin eyi lo gbina, to si jona gburugburu.
Mẹrin ninu awọn to wa ninu ọkọ naa ni wọn ku loju-ẹsẹ, nigba ti awọn meje fara pa yannayanna, ti ori si ko awọn to ku ninu ọkọ naa yọ.
Ọga ẹṣọ ojupopo yii ṣalaye pe mẹfa ninu awọn to fara pa naa ni wọn gbe lọ si ọsibitu jẹnẹra ijọba ni Kwara, nigba ti wọn gbe ẹni kan ninu wọn lọ si ileewosan alaadani kan ni Ẹyenkọrin, nitosi Ogbomọṣọ. Ọsibitu ijọba n’Ilọrin, ni wọn gbe awọn oku to ku ninu ijamba naa lọ.