Aarẹ Muhammadu Buhari ti le awọn ọga ileeṣẹ ologun ilẹ wa danu, bẹẹ lo si fi awọn mi-in rọpo wọn loju-ẹsẹ.
Agbẹnusọ Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, lo sọ eleyii di mimọ ni ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Awọ to fi rọpo wọn ni Ọgagun Leo Irabor, olori awọn ọga ologun patapata nilẹ wa bayii, Ọgagun I. Attahiru, olori awọn ṣọja, Ọgagun A. Z Gambo, olori awọn ọmọ ogun oju omi, nigba ti Ọgagun l.O Amao di olori awọn ọmọ ologun ofurufu.
O waa dupẹ lọwọ awọn to ti wa nibẹ fun bi wọn ṣe ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn, ti wọn ṣi ṣiṣẹ takuntakun lori eto aabo.
Bẹẹ lo ki awọn ti wọn ṣẹṣẹ yan yii ku oriire, o si rọ wọn lati ṣiṣẹ takuntakun, ki wọn si jẹ olotitọ ati akikanju ninu iṣẹ ti wọn ṣẹṣẹ gba yii.