Awọn to fẹ ki Yoruba kú soko ẹru lo dana sun ile mi- Sunday Ìgbòho

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tí gbogbo aye mọ si Sunday Ìgbòho, ti fìdí ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn dana sun ile oun.

O ni awọn ti ko lọwọ nínú ilakaka oun lati gba iran Yoruba silẹ lọwọ awọn agbesunmọmi to n pa wọn, tó sì n fi ayé ni wọn lara lo wa nidii iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ ọhun ko le yi oun lọkan padà nínú ijijagbara ti oun dáwọ́ lé yìí.

Gẹgẹ bí Ọgbẹni Dapọ Salami ti i ṣe agbẹnusọ fún akínkanjú ọmọ Yorùbá náà ṣe fìdí ẹ mulẹ, ni nnkan bíi aago mẹta oru mọju aarọ yii ni wọn dana sun ile Sunday Ìgbòho.

Iṣẹlẹ to dun ni jọjọ yii waye lẹyin ọjọ mẹta ti Igboho Ooṣa lọ sí ilú Igangan lati lọọ le awọn apaayan atawọn ajinigbe to wa laarin awọn Fúlàní kuro lagbegbe Ìbàràpá ati ni ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

Gbogbo ọmọ ọkọ Yorùbá ní wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun sí Igboho bayii, ti wọn sì n gbadura fun un pe Ọlọun yóò fòfò rẹ̀mí.

Leave a Reply