L eyin wakati diẹ ti wọn kọ lu agọ ọlọpaa, awọn janduku tun dana sun ile rẹpẹtẹ n’Ibadan

Lẹyin wakati diẹ ti wọn kọ lu agọ ọlọpaa, ninu eyi ti eeyan meji ti dagbere faye, nnkan bíi igba (200) ile lawọn tọọgi tun dana sun nigboro Ibadan loru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee.

Ọkọ bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tawọn ẹni ẹlẹni wa gunlẹ si ẹgbẹ titi lo bajẹ kọja atunṣe nigba ti ina ràn mọ wọn, ti awọn ipata ọmọ naa sì fi kondo ati apola igi da batani si awọn kan ninu wọn lara.

Iṣẹlẹ yii waye laduugbo Labiran, n’Ibadan, laarin aago mọkanla alẹ si aago meji oru mọju ọjọ Ẹti.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, iwa bàsèjẹ́ ọhún lawọn ọdọ agbegbe Labiran, Bẹẹrẹ, Ọja’ba atawọn agbagbe to sun mọ wọn hu gẹgẹ bíi ifẹhonu han wọn si bi awọn adari àdúgbò wọn pẹlu ijọba ṣe ṣèlérí fún wọn, ṣugbọn ti wọn ko ti i mu ileri ọhun ṣẹ.

Nitori yánpọnyánrin ti awọn ọdọ wọnyi saaba máa n da silẹ, eyi to máa n la ẹmi ati dukia lọ, lo jẹ ki ọga awọn Amọtẹkun lo awọn mọgaji àdúgbò kọọkan láti pe awọn ọdọkunrin agboole wọn si ìpàdé alaafia.

A gbọ pe ninu ipade ọhun nijọba ipinlẹ Ọyọ, nipasẹ ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ naa ti fun awọn ọmọ iṣọta wọnyi lanfaani lati sọ ohun ti wọn ba fẹ lati le dẹkun ija àjà-kú-akátá, ṣugbọn ti wọn kò padà mu ileri naa ṣẹ lẹyin ti wọn ti ṣadehun fún wọn.

Olugbe adugbo Labiran kan to fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju funra ẹ ti i ṣe oludari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ lo darí ìpàdé ọhún to waye ninu oṣù Kejìlá, ọdún 2020.

Ọkunrin tí kò darukọ ara ẹ foniroyin yii ṣalaye pe “Lati igba naa lawọn ọdọ yìí ti sinmi wahala ti wọn máa n fa kaakiri adugbo lojoojumọ ko too di pe wọn tun pada sidii ẹ nitori pe ijọba ko mu adehun rẹ ṣẹ fún wọn gẹgẹ bii ariwo ti wọn n pa kiri lẹnu ọjọ mẹta yii.”

Lati irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe wahala ọhun ti bẹrẹ, nigba ti awọn ọmọ iṣọta deede ko àdá ati apola igi jade bíi igba ti wọn n gbe eegun. Eyi ló da sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ sílẹ loju ọna Bẹẹrẹ sí Idi-Arẹrẹ, n’Ibadan, nigba tawọn eeyan, titi dori awọn awakọ ero atawọn ọlọkada n sá àsálà fún èmí ara wọn pẹlu eré àkọlùkọgbà.

Leave a Reply